Wọ́n pé Ìyá ọmọ ọdún mẹ́fà tó gbébọn lọ sílé ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́jọ́, wo ǹkan tó bá bọ̀ níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook
Awọn ọlọpaa orilẹede Amẹrika tifi panpẹ Ọba mu iyaọmọ ọdun mẹfa kan lẹyin ti ọmọ rẹ mu ibon wa si ile iwe alakọbẹrẹ rẹ ni ilu Virginia.
Ki ṣe igba akọkọ ti irufẹ iṣẹlẹ yii o waye lorilẹde Amẹrika.
Wọn pe ọlọpaa wa si ile iwe Elementary Little Creek nilu Norfolk nibiti awọn oṣiṣẹ ile iwe naa ti fun wọn nibọn na.
Ko si ẹnikankan to farapa ninu ile iwe na sugbon,iya kan sọ wi pe ọmọkunrin na halẹ lati yinbọn si ọmọbinrin rẹ ni kilasi wọn.
Ni oṣu to kọja ọmọ ọdun mẹfa miiran yinbọn mo oluko rẹ ni kilasi.

Oríṣun àwòrán, Michealfleshman
Ninu iṣẹlẹ tuntun yi iya ọmọ odun mẹfa na ni o ti foju ba ile ẹjọ lọjọ ẹti fun ẹsun fifi ibọn sibiti ọmọde ti ri,ile iṣẹ BBC ko darukọ iya ọmọ na lati daabo bo orukọ ọmọ naa.
Iya ọmọ ile iwe mii ni Elementary Little Creek sọ fun ile iṣe iroyin kan pe ọmọ naa mu ibọn ti ọta wa ninu rẹ wa si ile iwe ti o si fẹ yinbọn mo ọmọ oun lakoko ti wọn se ere idaraya.
Iṣẹlẹ yii lo farapẹ ti ọmọ ọdun mẹfa ni ilu Newport New Virginia,lọjọ kẹfa oṣu kinni ọdun yii to yinbọn mo olukọ rẹ Abby Zwerner ẹniti o ti pe ile iwe Richneck Elementary lẹjọ.
Iṣẹlẹ ibon yinyin Lamẹrika
Ninu Ọdun yii iṣẹlẹ ibon yiyin lorilẹde Amẹrika ti le ni aadọrin ti awọn eyi to lagbara julọ waye ni ilu California .
Larin ọdun mẹta sẹyin iṣẹlẹ ibọn yinyin ni gbagede lAmẹrika ti le ni ẹdẹgbẹrin.
Iṣẹlẹ ibon yinyin to lagbara julọ lAmẹrica lo ṣekupa eeyan aadọta ti eeyan ẹẹdẹgbẹta miran farapa.















