Tọkọtaya tí wọ́n yípadà láti akọ si abo àti abo sí akọ bí ọmọ tuntun ní India
Zahad ati Ziya ti di lọkọlaya akọkọ ni India ti wọn yoo bi ọmọ lẹyin ti wọn parada lati akọ si abo ati abo si akọ.
Awọn mejeji di gbajumọ lẹyin ti aworan wọn milẹ titi lori ayelujara ṣaaju ọjọ ikunlẹ.
Ziyal Praval, to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun ati ololufẹ rẹ, Zahad, to jẹ ẹni ọdun mẹtalalelogun ni awọn pinnu lati bimọ lẹyin ti wọn parada tan.
Arabinrin Paval to sọ pe o pẹ to ti wu oun lati finu ṣoyun ni wọn bi ni ọkunrin ko to yi ara rẹ pada si obinrin.
Nigba ti arakunrin Ahad, ti wọn bi ni obinrin parada si ọkunrin.
Lẹyin ti awọn mejeji yipada tan ni wọn pinnu lati bi ọmọ.
Ọpọ eeyan lori ayelujara lo ti bẹrẹ si n ki awọn eeyan naa ku oriire bayii lẹyin ti ẹjẹ ọrun naa foju ba ile aye.









