Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí èèyàn 36, ilé 50 dà wó ní Brazil

Oríṣun àwòrán, Screengrab/BBC
O le ni eeyan ẹrindinlogoji to ti padanu ẹmi wọn nibi iṣẹlẹ omiyale to waye ni ilu Sao Paulo orilẹede Brazil.
ọpọlọpọ lo ti di awati, o ṣeese ki awọn to padanu ẹmi wọn si iṣẹlẹ naa pọ si, awọn adola ẹmi n se iṣẹ takuntakun lati doola ẹmi awọn to wa labe ẹrọfo laye.
Aworan fi bi omi ti gba gbogbo oju opopona kan ti o si tun wọ awọn ọkọ ayọkẹlẹ lo.
Ni ilu Sao Sebastiao ojo to to iwọn 627mm lo rọ larin wakati mẹrinlelogun iwọn ojo to ye ko rọ fun oṣu kan.
Adari ilu naa Felipe August ni: iṣẹ idoola ẹmi n lo lọwọ oun ko le ti sọ odiwọn ohun to bajẹ ninu ilu São Sebastião.

Oríṣun àwòrán, Screengrab/BBC
Felipe ni aadọta ile lo ti dawo, akọsilẹ ijọba fihan pe o le ni eeyan aarundinlogoji ti wọn padanu ẹmi wọn ni São Sebastião ati Ubatuba, ninu wọn ni ọmọ ọdun mẹjo ti okuta ribiti ti gbẹmi rẹ.
Gomina ilu naa Tarcísio de Freitas ti yonda miliọnu kan aabọ dọla lati ṣe iranwọ fun awọn ti iṣẹlẹ omi yale ṣakoba.
Gbogbo ayẹye ọlọjọ marun to ma n wa ṣaaju ayẹyẹ awẹ lẹnti ni wọn ti wọgile.
Aarẹ Luiz Inácio Lula da Silva ti orilẹede Brazil wa ni ilu Bahia ọkan ninu awọn ilu ti iṣẹlẹ omiyale ti waye,yo ṣe abẹwo si awọn ibiti iṣẹlẹ naa ti waye.
Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ Aarẹ Luiz Inácio Lula da Silva ṣeleri lati pese ilera ọfẹ fun awon to fara kaaṣa iṣẹlẹ na.
O ṣeese ki ọpọn ojo rọ ni awọn agbegbe naa eyi ti o le mu ki isẹ idoola ẹmi lewu si.
Lọdun to kọja eeyan ọgbọn leni igba lo padanu ẹmi wọn ninu ojo arọmada nilu Petropolis
Brazil.















