Ìyá Dada tó pa ara rẹ̀ l'Ogun nítorí gbèsè N70,000 kìí ṣe oníbáràá wa- LAPO

Oríṣun àwòrán, Others
Banki alabọde LAPO microfinance Bank ti sọ pe arabinrin to da ina sun ara rẹ ni ipinlẹ Ogun nitori aile san gbese ẹgbẹrun lọna aadọrin naira (N70, 000) to ya kii ṣe onibara awọn.
Atẹjade kan ti adele adari eto ibaraẹnisọrọ ni banki LAPO, Abel Ovenseri lo yọju eyi sita.
Ni ọsẹ to kọja ni iroyin jade pe arabinrin kan ti awọn eeyan mọ si Mama Dada da ina sun ara rẹ ninu ile to n ya gbe nilu Abẹokuta nitori aile ri gbese ẹgbẹrun lọna aadọrin naira (N70, 000) to ya san pada.
Awọn to sọrọ naa nigba naa sọ pe banki alabọde LAPO MFB
Atẹjade naa to wa loju opo twitter banki naa sọ pe iwadii awọn ti fihan pe arabinrin naa,
Mama Dada kii ṣe onibara awọn ati pe banki miran lo ba dowo pọ, ṣugbọn adapọ orukọ lo mu ki awọn eeyan kan maa ro pe banki alabọde LAPO ni.
Banki naa ba a
wọn ẹbi ologbe naa daro ẹni wọn to lọ, bẹẹni wọn tun koro oju si awọn eeyan kan ṣe fẹ ba orukọ banki naa jẹ.
“Lẹnu ọdun diẹ sẹyin, iye awọn to n fi iru ẹsun bayi kan LAPO MFB n fi igba gbogbo pọ sii nitori wọn ni erongba ti wọn n lepa.”
O ni Banki LAPO ti n gbe igbesẹ ofin lori awọn to n gbe ẹsun eke dide sii laipẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post

Oríṣun àwòrán, Others
Nítorí owó gbọ́mú-lé-lantern l'obìnrin kan ṣe gbẹ̀mí ara rẹ̀ nípìnlẹ̀ Ogun
Arabinrin kan ti wọn mọ orukọ rẹ si iya Dada lo ti dana sun ara rẹ ninu ile ti wọn ya gbe lẹyin ti ko ri owo gbọmule lantern ẹgbẹrun lọna adọrin naira to ya san pada.
Iṣẹlẹ naa lo waye lagbegbe oke-meesi,Itoko Abeokuta nibiti obinrin na ti jona raurau ti ile naa jona pẹlu rẹ.
Ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ, Bolanle Ajayi ṣalaye pe Iya Dada mọọmọ pa ara rẹ nitori ailẹ san owo to ya ni banki.
Arabinrin miran ti o wa nibi iṣẹlẹ na Iyafin Adeogun ni ọpọlọpọ iwọsi ni wọn fi maa n kan ẹnikeni ti ko ba ri owo san pada nigba ti o ye.
Adeogun ni “to ba kọ lati san owo to ya pada nigba ti o ṣeleri wọn a fi ẹ ṣe ẹlẹya,gbogbo ara adugbo a ma oun to ṣe,yeye rẹ a po ati jade ma di ogun”.
Adeogu tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe awọn ọmọ ẹgbẹ nikan ni ajọ naa fun ni owo,
O ni sisan owo pada le jẹ lẹkan ṣoṣo tabi diẹ diẹ ikuna lati san owo naa ma un mu itiju dani.
Akọwe idagba soke agbegbe naa Ade Babawale fidi rẹ mulẹ pe Iya Dada n je owo to too ẹgbẹrun lọna adọrin naira
Babawale ni airi owo san lo fa ti Iya Dada ṣe dana sun ara rẹ.
O ni Iya Dada ran abikẹyin rẹ ni epo bẹntiro ti o si fi ọgbon ran an niṣẹ ko le jade kuro ninu ile
lẹyin eyi ni o da epo bẹntiro si inu ile ati ara rẹ ti ile na si gbana oun pẹlu ku sinu ile naa.
Wọn ti gbe oku rẹ lọsi ile iwosan ti ijọba ni,Ijaye Abeokuta.















