Àwoͅn oní màgòmágó ló fi ìròyìn òfegè sórí Facebook, Instagram mi– Aisha Buhari

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Iyawo aareͅ lorileͅede Naijiria, Aisha Buhari ti da eͅbi ru awoͅn oni magomago , ‘hackers’ pe awoͅn ni woͅn fi iroyin eͅleͅjeͅ si ori eͅroͅ ayelujara ati awoͅn oju opo idoͅreͅsoͅreͅ reͅ.

Iyawo aareͅ naa ni eleyii yoo jeͅ igba ikeͅyin ti oun yoo fi oͅroͅ lede lati tako iroyin eͅleͅjeͅ lori ikanni oun.

Iroyin ofege oͅhun lo niise peͅlu owo naira tuntun ati igbeseͅ naira atijoͅ ati naira tuntun.

Kini iroyin ofege to wa loju opo Facebook, Instagram iyawo aareͅ?

Iroyin ofege naa ti woͅn fisi oju opo Instagram ati Facebook iyawo aareͅ naa ni Oͅjoͅ koͅkanlelogun, Osͅu Keji, oͅdun 2023 naa sͅ wipe ijoͅba ti sun gbedeke sisun owo atijoͅ siwaju ni Naijria.

Atipe ijoͅba ti gba awoͅn eniyan laaye lati na owo naira atijoͅ 200, 500 ati 1000 titi di Oͅjoͅ Kini, Osͅu Karun un, oͅdun 2023.

Bakan naa ni iroyin ofege naa gba awoͅn oniroyin nimoͅran lati se apinka iroyin oͅhun.

Amoͅ ko peͅ leͅyin ti iroyin naa beͅreͅ si ni ja ranyin ni banki apapoͅ Naijiria gbe iroyin jade pe ko si ohun to joͅ igbeseͅ tuntun naa to wa loju opo ikansiraeͅni iyawo aareͅ.

Ohun ti CBN, Aisha Buhari soͅ lori iroyin ofege naa…

Banki apapoͅ Naijiria ti fesi si iroyin ofege loju opo iyawo aareͅ orileͅede Naijiria, Aisha Buhari.

CBN kesi awoͅn oͅmoͅ Naijiria lati tabuku iroyin naa nitori oͅroͅ aareͅ Buhari to soͅ pe 200 naira atijoͅ nikan ni awoͅn eniyan le n ani awoͅn teͅle.

Bakan naa ni iyawo aareͅ fi si oju ikansiraeͅni reͅ pe awoͅn oͅbayejeͅ lo sͅatako si oju opo reͅ.

Aisha Buhari ni woͅn feͅ ba orukoͅ oun jeͅ lori ayelujara ni woͅn se gbe igbeseͅ naa.