Cyclone Freddy: Àwoͅn ará Mozambique 600,000 gbáradì fún ìjì líle

Oríṣun àwòrán, Others
O kere tan awon ara orileͅede Mozambigue to le ni eͅgbeͅrun loͅna eͅgbeͅta ni yoo faragba ninu iji lile cyclone Freddy to seese to beͅ sileͅ ni agbegbe omi nibeͅ.
Ijoͅba orileͅede Mozambigue kede awoͅn agbegbe ti yoo faragba naa ni Zambezi, gbungbun orileͅede naa ati guusu orileͅede naa.
O kere tan awoͅn eniyan eͅgbeͅrun loͅna eͅgbeͅrun ni woͅn yoo niloͅ iranwoͅ ijoͅba ti iji lile naa ba ableͅ peͅlu agbara.
Adari ileesͅeͅ ijoͅba to n risi oͅroͅ omi, Agostinho Vilanculos lo kede beͅeͅ.
O sapejuwe iji lile Cyclone Freddy ti woͅn n reti naa geͅgeͅ bi eleyii ti yoo mu ateͅgun lile dani, eleyii ti yoo fa oͅpoͅloͅpoͅ ijamba fun awoͅn eniyan.
Ni agbegbe Beira, awoͅn olugbe agbegbe naa ti n da abo bo ara woͅn nipa gige awoͅn igi to wa lagbegbe woͅn.
Iyeͅn nikan kan, woͅn ko iyeͅpeͅ sinu apo ati awoͅn irin lati jeͅ ki ile woͅn duro deede lati koju iji lile naa.
Bakan naa ni woͅn ti n ko ounjeͅ ati omi pamoͅ to fi moͅ imoͅleͅ ati lantern fun awoͅn eniyan.
Awoͅn ileeͅkoͅ di titi pa saaju iji lile cyclone
Awoͅn alasͅeͅ lorileͅede Madagascar ti kede pe awoͅn ti ti awoͅn ileeͅkoͅ pa lorileͅede naa.
Woͅn ni eyi ko sͅeͅyin iji lile Cyclone Freddy ti o seese ko baleͅ si orileͅede naa ni oͅseͅ yii.
Eͅka pajawiri lorileͅede naa ni titi ileeͅkoͅ naa pa yoo mu adinku ba irinajo ati liloͅ biboͅ lasiko yii.
Bakan naa ni woͅn kede pe woͅn ti fi awoͅn ohun elo ti yoo mu ile duro ni asiko yii ati ohun elo ounjeͅ si awoͅn agbegbe to sͅeese ki ipa iji lile naa ti poͅju bo se yeͅ loͅ.
Awon alaseͅ naa ni agbegbe omi Mauritius ti faragba lara ojo aroͅoͅda to waye ni Oͅjoͅ Aje.












