Akẹ́kọ̀ọ́ gún olùkọ́ rẹ̀ pa ní kíláàsì, ètò ẹ̀kọ́ dàrúo!

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ girama kan ti wọ kilaasi lọ gun olùkọ́ rẹ pa ni agbegbe Saint-Jean-de-Luz ni orileede Faranse.
Agbenuso Ijoba orileede naa, Olivier Veran fi aridaju iṣẹlẹ naa han to si ni ọmọ ile ẹ̀kọ́ to ṣiṣẹ́ ibi yii jẹ ọmọ ọdun merindinlogun.
Ọlọpaa ti lọ si ile ẹ̀kọ́ naa nibi ti wọn ti fi panpẹ òfin mu akẹ́kọ̀ọ́ náà.
Gẹgẹ bi ìwé iroyin ilẹ̀ Faranse kan, Sud Ouest ṣe jabọ, ọmọ naa dede wọ inu kilaasi lasiko ti olùkọ́ n kọ imọ ẹ̀kọ́ èdè Spanish lọwọ o si ṣe ikọlu sii.
Iroyin ni olùkọ́ naa jẹ ẹni to le díẹ̀ ni aadọta ọdun to si pada ku latari ikọlu ọkan eyi to ṣẹlẹ̀ lẹyin ti ọmọ naa gun un lọbẹ.
Bákan naa, ile isẹ amohunmaworan ilẹ̀ Faranse, BFM sọ pe ọmọ naa ti ilẹkun kilaasi pa o si lọ gun olùkọ́ rẹ laya.
Iwadii ti n lọ lọwọ bayii lọdọ awọn Ọlọpaa lori ẹsun ipaniyan bẹẹ si ni afurasi ọhun ti wa ni àtìmọ́lé. O fi kun un pe afurasi naa kii ṣe eeyan ti Ọlọpaa tabi ile ẹjọ́ mọ tẹ́lẹ̀.
Minisita eto ẹ̀kọ́ ilẹ̀ Faranse, Pap Ndiaye ṣe apejuwe ikọlu naa gẹgẹ bii eyi to buru jai to si fi ọrọ ibanikẹdun rẹ ránṣẹ́.
"Oni jẹ ọjọ ikẹdun", o sọ eyi lasiko to ṣe ibewo si ile ẹ̀kọ́ naa. Gbogbo araalu lo wa nibi lati fi ẹdun ọkan wọn hàn."
Awọn oniroyin abẹle ròyìn pe o seese ki ọmọ naa ni ipenija aisan ọpọlọ tori nibi ti wọn ba iwadii wọn dé, wọn ni iṣẹlẹ naa ko ni nkankan ṣe pẹlu iwa ipa.
Níbi ipade oniroyin kan, Ọgbẹni Veran sọ pe ijọba yoo ṣe iranlọwọ fun awọn eleto ẹ̀kọ́ kaakiri orileede naa lori iṣẹlẹ yii.
Ile ẹ̀kọ́ naa jẹ ti aladani eyi ti ìjọ Katoliki da silẹ ni ẹgbẹ Saint-Jean-de-Luz, agbegbe to gbajumọ daadaa lorileede Faranse.
Nigba to fi di akoko ìjẹun, awọn ti wọn ti ni ki wọn jókòó sinu kilaasi wọn ri aaye jade kuro ninu ọgba ile ẹ̀kọ́ ti awọn obi si wa ko ọpọlọpọ.












