Wooden sex toy found: Àṣé nǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ oní igi ti wà lọ́jọ́ pípẹ́? Ẹ wo ìtumọ̀ ara rẹ̀ tó ń dán gbiirin yìí

Àṣé nǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ oní igi ti wà lọ́jọ́ pípẹ́? Ẹ wo ìtumọ̀ ara rẹ̀ tó ń dán gbiirin yìí

Nnkan iṣere ibalopọ onigi

Oríṣun àwòrán, THE VINDOLANDA TRUST

Ni agbegbe Hadrian’s Wall nilẹ Romu ni wọn ti ri nnkan iṣere ibalopọ onigi to jẹ kayefi yii eyi ti wọn kọkọ ro pe irinṣẹ aranṣọ ni amọ ti wọn ṣawari pe o ṣeeṣe ko jẹ nnkan iṣere ibalopọ lasiko Century keji lọhun.

Awọn akọṣẹmọṣẹ ṣalaye pe nnkan elo ti wọn ri yii ni Vindolada lee jẹ apẹrẹ ere nnkan nnkan ọmọkunrin nigba iwasẹ ti eeyan lee ri nibikibi ni igba ijọba Roomu atijọ.

Ẹwẹ, wọn ni awọn ko tii yi ohun pada lori pe o ṣeeṣe ko jẹ ami nnkan daadaa tabi irinṣẹ fin gigun nnkan.

Lakọkọ, wọn lero pe ohun elo kan ti wọn fi n ṣe atunṣe nnkan ni ti wọn si rii laarin ọpọlọpọ bata.

Bakan naa ni wọn ri awọn nnkan ẹṣọ ara atawọn ohun elo kekeke mii pẹlu rẹ pẹlu awọn ageku awọ lẹda ni ilẹ lẹgbẹ Hwxham ni ilu Northumberland.

‘O n dan gbiinrin lori ati nisalẹ’

Igi

Oríṣun àwòrán, THE VINDOLANDA TRUST

Awọ onimọ lati Fasiti Newcastle ati Ile ẹkọ girama ti Fasiti Dublin sọ pe awọn ti wa gbagbọ pe igi naa to jẹ iwọn Centimetere mẹrinla (5.5in), ṣeeṣe ko jẹ ohun ti wọn n lo ninu ara gidi gan ni.

Nigba ti wọn gbe e yẹwo daadaa, wọn woye wọn si rii pe oke ati isalẹ rẹ n dan daadaa, eyi to fihan pe wọn lo o lọpọ igba.

Dokita Rob Collins to jẹ olukọ agba ninu imọ wiwa ilẹ ni Fasiti Newcastle sọ pe: “A mọ pe awọn eeyan Roomu ati Greeki nigba iwasẹ lo awọn nnkan ibanilopọ - ohun elo yii ti wọn si ri lati Vindolanda lee jẹ apẹrẹ ọkan lara wọn.”

“Phalli, jẹ́ ohun to wọpọ gan ni ijọba Roomu igba naa tori wọn gbagbọ pe o maa n daabo bo eeyan kuro lọwọ oriibu.

Roomu

Oríṣun àwòrán, VINDOLANDA TRUST

Ọpọ wọn maa wa bii iṣẹ ọna, ti wọn gbẹ bii ikoko tabi ohun ti wọn gbẹ latara egungun tabi irin ti wọn si saba maa n wọ bii ẹgba ọrun.

Awọn onimọ nipa wiwa ilẹ sọ pe nkan mii to ṣeeṣe ko jẹ ni pe wọn n lo igi naa gẹgẹ bii ọmọ odo ti wọn fi n gun awọn nnkan iṣara loge tabi oogun ti wọn si lero pe irisi rẹ jọ eyi ti yoo ni agbara alupayida.

Tabi wọn o lee jẹ pe wọn sọ ọ ti ere ti wọn si mu ara rẹ dan fun ẹni to ba fẹ loo fi ṣe kongẹ oriire. Wọn kọ eyi sinu iwe iroyin igbadegba “Antiquity”.

Barbara Birley, to jẹ olupa aṣa mọ ni Vindolanda Trust nibi ti igi naa wa bayii sọ pe: “Igi to dabi nnkan ọmọkunrin yii lee jẹ ara ọtọ pẹlu bo ṣi ṣe wa laye lati igba rẹ, ṣugbọn ko le jẹ pe ohun nikan ni iru rẹ to maa wa nibi ti wọn ti rii tabi ni ilẹ Roomu gan.”