Joy Adekunle Adejare: Torí òkìkí tí mo ní nídìí iṣẹ́ àgbo ni wọ́n ṣe jí ọkọ mí gbé, wọ́n sì pa á
Ọpọ ọdọ laye ode oni lo maa n mọ isẹ tewe-tegbo loju, ti wọn si maa n ri isẹ awọn alagbo bii ohun idọti, ti ko se sunmọ.
Sugbọn Yoruba ni ori lo mọ isẹ asela nitori riro ni ti eniyan, sise ni ti Ọlọrun ọba.
Obinrin kan ree, Joy Adekunle Adejare to yan isẹ Nọọsi olutọju alaisan laayo nibẹrẹ aye rẹ amọ to pada wa di olokiki lati ipasẹ agbo sise.
Isẹ ajogunba ni isẹ tewe-tegbo fun Joy nitori o jogun ba lọwọ baba rẹ ni.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Joy Adekunle Adejare salaye bo se kọkọ fariga lati tẹwọ gba isẹ naa lọwọ baba rẹ.
O ni oun yi ipinnu oun pada nigba ti oun n ri bi ewe ati egbo ti n se gudugudu meje ati yaaya mẹfa nidi iwosan awọn alaisan
"N ko kabamọ rara pe mo pada gba lati maa sisẹ tewe-tegbo nitori gbigba ẹmi awọn eeyan la jẹ mi logun.
Bẹẹ si ni iwe ti mo ka ati imọ nipa isegun oyinbo ti mo ni, tun ran mi lọwọ lati mase maa fi oogun ori fifọ, wo inu rirun nidi tewe-tegbo ti mo n se.
Joy, ẹni to mu BBC Yoruba lọ yika ileesẹ to ti n sọ agbo di oogun onihoro ati olomi, wa fi ọwọ gbaya pe isẹ tewe-tegbo ti kọja pe a n kiri rẹ kiri lori atẹ.

Wọn ji ọkọ mi gbe nigba meji, wọn si paa nitori okiki ti mo ni nidi isẹ Tewe-tegbo
Nigba to n sọrọ lori awọn ipenija ti oju rẹ ri nidi isẹ agbo sise to yan laayo naa, se ni Joy bu sẹkun gbaragada.
O salaye pe oun lọ da ẹka ileesẹ apoogun tewe-tegbo kan silẹ nilu Portharcourt nipinlẹ Rivers.
O ni okiki oun kan pupọ nibẹ nitori bi oun se n se iwosan fun ọpọ eeyan, ti oun si n gba ẹmi ọpọ alaisan la.
- Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin Foluke Daramola àti Páátọ̀ Agbala Gabriel tó ń kọ́lé fún Iya Ibeji Omo Arayele
- Wo Aláàfin tó bí ọmọ 1,460, ayaba mẹ́sàn-án bí ìbejì lọ́jọ́ kan ṣoṣo ní ìgbà mẹ́ta
- Ìyá, bàbá àti oͅmoͅ méjì wà lára àwọn tó kú nígbà tí ‘Container’ ṣubú lé oͅkòͅ akérò l‘Eko
- Ooni Ile ife, Adeyeye Ogunwusi di onítíátà nílẹ̀ Amẹ́ríkà
- Àwọn dókítà gbé ọ̀bẹ jádé nínú ilé ọmọ obìnrin kan lẹ́yìn ọdún 11 tó ṣiṣẹ́ abẹ
"Idi ree ti wọn se wa ji ọkọ mi gbe lakọkọ, ti mo si san owo ribiribi fun wọn lati doola ẹmi ọkọ mi.
Amọ wọn tun pada wa nigba keji, ti wọn si pa ọkọ mi, ka to le doola ẹmi rẹ, ipenija nla ni eyi jẹ fun mi, ti mo si pinnu lati fi isẹ tewe-tegbo naa silẹ.
Mo ko kuro nilu Portharcourt, ti mo si pada wa si Ibdan pẹlu ipinnu pe maa yan isẹ miran laayo sugbọn ẹbẹ awọn eeyan to n jẹ adun tewe-tegbo lọdọ mi, lo jẹ ki n yi ipinnu mi pada."