Olùdíje sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ àwọn agbébọn ní ìbò ku ọjọ́ kan, wọ́n tún dáná sun òkú rẹ̀

OYIBO CHUKWU

Oríṣun àwòrán, OYIBO CHUKWU/FACEBOOK

Bí ó ṣe ku ọjọ́ kan kí ètò ìdìbò gbogbogboò wáyé sí ipò ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti láti yan àwọn aṣojú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀, àwọn agbébọn ṣekúpa olùdíje sípò sẹ́nétọ̀ ìlà oòrùn Enugu lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Oyibo Chukwu.

Ní alẹ́ Ọjọ́rú ni àwọn agbébọn náà ṣekúpa Oyibo Chukwu lásìkò tó ń padà sílé lẹ́yìn tó lọ kópa níbi ètò ìpolongo ìbò kan ní ẹkùn gúúsù Enugu.

Lẹ́yìn tí àwọn agbébọn ọ̀hún fi ìbọn pa Oyibo Chukwu tán ni wọ́n tún dáná sun òkú rẹ̀ mọ́ inú ọkọ̀ tó wà.

Bákan náà ni wọ́n tún pa àwọn ènìyàn márùn-ún mìíràn tó wà nínú ọkọ̀ pẹ̀lú Oyibo Chukwu.

Agbẹnusọ Chukwu, Chijoke Ogbodo nígbà tó ń bá BBC Igbo sọ́rọ̀ ní lẹ́yìn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé tán ni òun tó gbọ́ nípa rẹ̀.

Ogbodoní ọ̀gá òun ń bọ̀ láti ibi ìpàdé kan tó lọ ní Agboani ní ìjọba ìbílẹ̀ Nkanu-West ní àwọn agbébọn náà ṣe ìkọlù si.

“Ohun tó dùn mí jùlọ nínú ìkọlù náà ni pé lẹ́yìn tí wọ́n pa wọ́n tán, wọ́n tún dáná sun wọ́n mọ́ inú ọkọ̀ tí wọ́n wà.”

“Ìṣekúpani yìí kìí ṣe àṣìṣe rárá nítorí Oyibo kò sí nínú ọkọ̀ tí wọ́n kó orúkọ rẹ̀ sí, àwọn ènìyàn náà tẹ̀le láti ibìkan kí wọ́n le ṣiṣẹ́ ibi wọn mni.”

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn IPOB/ESN ló wà nídìí ìkọlù náà – Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Enugu ní àwọn ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ikọ̀ tó ń jà fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ èdè Biafra ló ṣiṣẹ́ ibi náà.

Àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Enugu, Daniel Ciekwe fi síta lọ́jọ́bọ̀ ní àwọn oníṣẹ́ ibi náà tún ṣekúpa àwọn èèkan ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kan ní agbègbè Topland road ní Enugu ọ̀hún bákan náà.

Ciekwe ní Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Enugu, Ahmed Ammanien ti pàṣẹ pé kí àwọn ọlọ́pàá wá àwọn tó ṣiṣẹ́ ibi náà kàn ní kíákíá.

“A ní ìgbàgbọ́ pé àwọn ikọ̀ IPOB/ESN ló ṣe ìkọlù sáwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Labour Party àti APC níbi tí wọ́n ti ṣekúpa olùdíje kan, ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kan àti ṣíṣe ìkọlù sí olùdíje gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC ní Enugu.”

Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ọ̀hún ti ṣe àbẹ̀wò sí agbègbè tí ìkọlù náà ti wáyé.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Labour Party kọminú lórí ikú ọmọ ẹgbẹ́ wọn

Olùdíje sípò gómìnà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party ní ìpínlẹ̀ Enugu, Chijioke Edeoga nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìkọlù ọ̀hún ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn ni wọ́n ń fojú sí lára báyìí.

Edeoga ní bí ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ṣe ti ń rí ọwọ́ mú káàkiri ti ń ba ọ̀pọ̀ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú lẹ́rù ni wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní rán àwọn agbanipa sáwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn.

Àtẹ̀jáde tí Kingsley Moghalu fi léde

Oríṣun àwòrán, KINSLEY MOGHALU/TWITTER

Peter Obi bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà

Olùdíje sípò ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi ní nǹkan burúkú gbá à ni bí àwọn kan ṣe ṣekúpa Oyibo Chukwu.

Nínú àtẹ̀jáde kan tí Peter Obi fi sórí ayélujára Twitter rẹ̀ ní ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ fún òun nígbà tí òun gbọ́ nípa ikú Oyibo Chukwu tó jẹ́ olùdíje sípò sẹ́nétọ̀ ní ìlà oòrùn Enugu.

Ó ní àsìkò yìí kò yẹ kó wà fún irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí àmọ́ òun bá ẹbí àti ará Chukwu ní ìpínlẹ̀ Enugu àti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party kẹ́dùn lápapọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Àwọn nǹkan tí a mọ̀ nípa Oyibo Chukwu

OYIBO CHUKWU

Oríṣun àwòrán, OYIBO CHUKWU/FACEBOOK

Ògbóǹtarìgì olóṣèlú tó jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Enugu ni.

Ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́ta ni kí àwọn agbébọn tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.

Ní Abakaliki ni ìpínlẹ̀ Ebonyi ló ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama kó tó tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì University of Nigeria, Nsukka níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin.

Bákan náà ló ní ìrírí tó pọ̀ nípa òṣèlú tó sì díje sípò òṣèlú lọ́kan-ò-jọ̀kan.