Àlàyé rèé lórí ìdí tí EFCC kò fi tíì mú ẹnikẹ́ni fún kíkó Naira tuntun pamọ́

Aworan owo tuntun kan pẹlu aworan alaga ajọ EFCC Abdulrasheed Bawa

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, ijẹkujẹ ati ajẹbanu to n tigi boju ọrọ aje ati iṣuna ni Naijiria, EFCC ti ṣalaye idi ti ko maa fi tara ṣaṣa mu gbogbo awọn to n ko owo naira tuntun pamọ.

Paapaa pẹlu bi inira ọwọngogo owo naira tuntun igba naira olodindi (N200), ẹẹdẹgbẹta naira olodindi (N500) ati ẹgbẹrun kan naira olodindi (N1000) kaakiri orilẹede Naijiria.

Alaga ajọ EFCC Abdulrasheed Bawa ṣalaye ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan lorilẹede Naijiria pe ajọ naa mọ pe ọpọ awọn oniṣowo ti ọwọ wọn ko mọ kan ṣi ni awọn owo wọnyi ni ipamọ.

Amọṣa Bawa ni ofin Naijiria ṣi fi aye silẹ fun ẹnikẹni to ba ni awọn owo atijọ yii lọwọ lati lọ san wọn sinu aṣuwọn banki apapọ CBN lọjọ iwaju.

O ni idi ti awọn ṣi fi n wa ọwọ ro ni pe koko eto paṣiparọ owo to n lọ lọwọ ni lati rii daju pe awọn eeyan da owo ọwọ wọn pada sinu eto ifọwopamọ si orilẹede Naijiria.

“Bẹrẹ lati oṣu kẹwaa titi di asiko yii a ko tii mu ẹnikẹni bẹẹni a ko tii maa fimu finlẹ lori tani o ko iye owo bayii pamọ, lasiko wo ati nibo ni nitori a ko fẹ da họwuhọwu kankan silẹ.”

Amọṣa ọga agba ajọ EFCC ni ko si wahala rara fun ajọ naa to ba fẹ bẹrẹ iṣẹ nitori pe gbogbo awọn owo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ n gbe sita naa lo ni numba idanimọ ti ajọ naa lee fi tọpasẹ wọn ati ibi ti wọn pin wọn si kakiri Naijiria.

“A le e tọpaṣẹ boya ọna ẹtọ ni wọn gba ko owo wọnyi jade lati ẹnu ẹrọ apọwo ATM tabi boya ẹnikan lo ko wọn lọpọ yanturu fun awọn oloṣelu kan.”