Wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún olórí ilé aṣòfin Osun, àlàyé lórí bó ṣe móríbọ́ rèé

Aworan Timothy Owoẹyẹ, olori ile aṣofin ipinlẹ osun

Oríṣun àwòrán, Gbenga adeniyi

Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Họnọrebu Timothy Owoẹyẹ sa asala bọ lọwọ awọn kan ti ọpọ fura si pe wọn jẹ agbenipa lọjọru.

Ilu Ileṣa lawọn afurasi agbenipa naa ti kọlu Họnọrebu Owoẹyẹ; Ọpẹlọpẹ awọn ẹṣọ agbofinro rẹ lati ileeṣẹ ọlọpaa ati DSS ti wọn wa layika rẹ ni wọn fi ina ibọn fesi fun awọn afurasi agbenipa naa.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, agbẹnusọ fun olori ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ọṣun, Kunle Alabi ṣalaye pe nnkan bii agogo meji oru ni awọn afurasi agbenipa naa bẹrẹ ikọlu wọn ti wọn si bẹrẹ si nii yinbọn.

Iro ibọn ti awọn ẹṣọ alaabo rẹ gbọ ni awọn pẹlu fi ṣina ibọn pada eyi to mu ki awọn afurasi naa sare pada ninu ọkọ ti wọn gbe wa.

“Ọkọ bọọsi Hummer ni wọn gbe wa ti wọn si bẹrẹ si nii yinbọn si iyara ti olori ile aṣofin wa. Idi gan niyi ti a fi fura pe kii ṣe ọrọ adigunjale bikoṣe awọn to fẹ pa a. Ara ọta ibọn ti wọn yin gba ọgangan yara ti họnọrebu n sun wọle to si lọ ba aga to wa ninu yara naa.”

O fi kun un pe nigba ti awọn ẹṣọ alaabo yẹ awọn korofo ọta ibọn ti awọn agbenipa naa yin, o jẹ kogẹ ti AK 47 ti awọn ọlọpaa nlo eleyii ti ko si yẹ ko wa lọwọ ẹnikẹni ti kii ba ṣe oṣiṣẹ alaabo.”

Ninu ipade ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn akọroyin, olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Họnọrebu Timothy Owoẹyẹ fi kun un pe ko din ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC marun un ti awọn agbenipa ti ṣekupa lagbegbe Eti Ọni ni ijọba ibilẹ Atakumọsa East, Oke Aga ati Ilesa lẹnu lọwọlọwọ yii.

Aworan olori ile aṣofin Osun, Họnọrebu Timothy Owoẹyẹ

Oríṣun àwòrán, Gbanga adeniyi

“Mo kan sara si awọn ẹṣọ alaabo mi ti wọn duro digbi, bi kii ba ṣe tiwọn ni awọn agbebọn naa iba ti mu erongba wọn ṣẹ.

“Bakan naa lawọn kan sọ fun mi lowurọ yii pe eto ipese ina ti mo ti na bii miliọnu marundinlogun naira si fun awọn ara Oke Aga lawọn agbebọn kan tun lọ ṣi ina ibọn bo. “

Họnọrebu Owoẹyẹ ni gbọnmọgbọnmọ ikọlu awọn agbebọn ati janduku ni ipinlẹ Ọṣun lẹnu lọwọlọwọ yii n kọ ọpọ lominu.

Ki ni ọlọpaa sọ si ọrọ yii?

Aworan Họnọrebu Owoẹyẹ pẹlu kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, Gbenga Adeniyi

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun SP Yẹmisi Ọpalọla sọ pe afurasi mẹfa ni ọwọ ọlọpaa ti tẹ lori gbogbo wahala ati iwa ọdaran to n ṣẹlẹ Ileṣa ati agbegbe rẹ.

Amọṣa o ni ohun ko tii le sọ boya wọn niiṣe pẹlu ikọlu to waye si olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun, Họnọrebu owoẹyẹ.

Bakan naa ni SP Ọpalọla fidi rẹ mulẹ pe wọn ti ko ikọ ajumọṣepọ awọn agbofinro to ni oṣiṣẹ ajọ alabo bii ọlọpaa DSS, awọn ologun, sifu difẹnsi atawọn miran kaakiri awọn ibu ati oro ipinlẹ naa ki wọn le tubọ mojuto ọrọ abo ni ipinlẹ naa.