Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ kí wọ́n ti gbogbo ẹnubodè ilẹ̀ tó wọ Naijiria fún wákàtí mẹ́rìnlélógún

Oríṣun àwòrán, @DefenseNigeria
Ileeṣẹ aṣobode Naijiria, Nigeria Immigration Service, NIS, ti paṣẹ ki wọn ti gbogbo ẹnubode ori ilẹ to wọ Naijiria lọjọ Abamẹta ti idibo Aarẹ ati ile igibmọ aṣofin yoo waye.
Ọga agba ileeṣẹ naa, Isah Jere Idris, lo paṣẹ bẹẹ ninu atẹjade kan to fi sọwọ gbogbo ẹka ileeṣẹ ọhun, ati lori ayelujara.
Atẹjade naa ni “Ijọba apapọ ti paṣẹ ki a ti gbogbo ẹnubode ori ilẹ to wọ Naijiria lati aago mejila oru, ọjọ Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023.”
“Ibode naa yoo si wa ni titi di aago mejila oru ọjọ Aiku, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023.”
“Fun idi eyii, gbogbo ẹka ileeṣẹ wa, paapaa awọn ipinlẹ to sun mọ ibode gbọdọ fidi aṣẹ yii mulẹ.”
Loju opo Twitter, NIS sọ pe ojuṣe awọn ni lati daabo awọn ọmọ Naijiria lasiko eto idibo naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
NIS ni “A ti pinu lati ṣe ojuṣe wa ki Naijiria le dara.”
“A o ṣe gbogbo ohun to ninu agabra ti ofun fun wa lati ri daju eto idibo naa ko ni magomago ninu.”
Ero awọn araalu ṣọtọtọ
Ẹwẹ, ni kete ti NIS fi atẹjade naa lede loju opo Twitter lawọn eeyan bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lede lori igbesẹ ọhun.
Bi awọn kan ṣe n sọ pe ohun to dara ni, lawọn mii n sọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ.
Awọ miran tilẹ sọ pe o ṣeeṣe ki NIS ma ti ẹnubode Ariwa Nigeria, eyii to lọ si Chad ati Niger.












