Ẹ gba kámú lórí ẹni tí INEC bá kéde pé ó wọlé, àlááfíà Nàìjíríà ni mo fẹ́- Buhari

Aworan Buhaari

Oríṣun àwòrán, muhammedBuhari/Facebook

Aare Muhammadu Buhari ti rọ gbogbo awọn oludije sipo aarẹ ọdun yi lati gba abajade esi idibo ki wọn si bọwọ fun ẹnikẹni ti awọn eeyan diboyan

O sọrọ na nilu Abuja nibi ibuwọlu ẹẹkeji ti ajọ National Peace Accord ṣe fun awọn ẹgbẹ oselu ati awọn oludije si ipo aarẹ.

Aarẹ Buhari rọ eyikeyi oludije ti o ba ni ikun sinu lati lo awọn ilana ofin ,o rọ wọn lati ni igbẹkẹle ninu eto ofin orilẹ-ede yii.

Aarẹ Muhammadu Buhari ninu ọrọ rẹ ni “Mo bẹ ẹyin oludije ti o n dije ninu awọn eto idibo wọnyi ni gbogbo awọn ipele lati bọwọ fun abajade ibo ẹ si gba esi ibo gẹgẹ bi INEC ile-iṣẹ ti ofin fun ni agbara lati ṣe bẹ ti kede”.

Aarẹ tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ wi pe “lẹkan si mo rọ ẹyin oludije lati bọwọ fun akọsilẹ ati ẹjẹ ti e fọwọ si loni”.

O gboriyin fun ajọ NPC fun ilakaka rẹ lati ri wi pe alafia wa saaju ati lẹyin eto idibo pẹlu bi wọn se gbara lẹ ijọba kankan lati gbe awọn eto wọn kalẹ.

Buhari ni eti oun ti kun fun ọpọlọpọ ọrọ boya eto idibo ọdun yii ma waye ati oun to le ṣẹlẹ lẹyin eto idibo.

O ni “latigbati wọn ti bura fun mi gẹgẹ bi aarẹ,ijọba mi n siṣẹ takuntakun lati ri wi pe gbogbo eto idibo ti ijọba yii ṣe lo kẹsẹjari ti o si lo ni irọwọrọsẹ.

Buhari lo apẹrẹ eto idibo Edo,Ondo,Anambra,Ekiti ati Osun se apere awọn eto idibo to ti kẹsẹjari lai si atoju bọ ijọba apapọ,o ṣeleri lati pe ijọba oun ko ni gbe lẹyin ẹgbẹ oselu kankan.

Aarẹ Buhari lu ago ikilọ fun awọn to ṣetan lati da wahala silẹ lẹyin ipolongo ẹni to jawe olubori ninu eto idibo lati so ewe agbeje mọwọ,ti o si rọ awọn to ba fẹ fọwọ janu lati gba ile ẹjọ lo.