Ilé ẹjọ́ Supreme Court mú March 3 fún ìdájọ́ ẹjọ́ tí ipínlẹ̀ mẹ́wàá pe ìjọba àpapọ̀ lórí pàṣípààrọ̀ owó náírà tuntun

Aworan ile ẹjọ Supreme Court ati owo ẹgbẹrun kan naira odindi atijọ

Oríṣun àwòrán, other

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria, Supreme court ti sun ẹjọ si ọjọ kẹta oṣu kẹta ọdun 2023 lori ẹjọ ti awọn ijọba ipinlẹ mẹwaa pe tako ijọba apapọ lori ilana ṣiṣe eto paṣipaarọ owo naira tuntun ti wọn pe niwaju rẹ.

Ile ẹjọ to ga julọ naa ni ọjọ kẹta oṣu kẹta yii lawọn yoo gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ naa lẹyin ti wọn ṣe adapọ ipẹjọ awọn ipinlẹ meje miran pẹlu mẹta to pe ẹjọ naa ni ibẹrẹ pẹpẹ.

Supreme court da ẹjọ́ ìpínlẹ̀ mẹ́wàá tó tako Buhari lórí ọ̀rọ̀ àyípadà naira pọ̀
Aworan abawọle Supreme court naijiria

Oríṣun àwòrán, other

Ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti gba lati da ẹjọ ti awọn ijọba ipinlẹ mẹwaa pe tako ijọba apapọ lori ọrọ ayipada owo naira pọ si oju kan naa.

Nibi igbẹjọ rẹ lọjọ karundinlogun oṣu keji ọdun 2023, awọn ijọba ipinlẹ meje kan pẹjọ lati darapọ mọ ipẹjọ ijọba ipinlẹ mẹta akọkọ to pẹjọ tako ijba apapọ lori ẹjọ naa niwaju ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, ti ijọba ipinlẹ Bayelsa ati Edo si darapọ mọ ijọba apapọ gẹgẹ bi olujẹjọ.

Ọpọ lo ti n reti abajade igbẹjọ ile ẹjọ to ga julọ ni nAijiria lori ọrọ ayipada owo naira eyi to ti n fa ọpọ inira fun araalu ṣaaju asiko yii.

Amọṣa ile ẹjọ naa ko gba ẹjọ ti ijọba ipinlẹ Abia lati darapọ mọ awọn olupẹjọ wọle nitori wọn ni o pẹ diẹ ki wọn to fi iwe ẹjọ wọn ṣọwọ si ile ẹjọ naa.

Nibayii awọn olupẹjọ ninu ẹjọ naa ni awọn agbẹjọro agba ipinlẹ Kaduna, Kogi, Ekiti, Zamfara, Ondo, Katsina, Ogun, Cross river, Sokoto ati ipinlẹ Eko nigba ti awọn olujẹjọ yoo jẹ agbẹjọro agbaorilẹede Naijiria, Abubakar Malami, (SAN) atawọn agbẹjọro agba ipinlẹ Bayelsa ati Edo.

Bawo lọrọ yii ṣe bẹrẹ?

Aworan gomina ipinlẹ Zamfara, Kogi ati Kaduna

Oríṣun àwòrán, twitter/Zamfara state/kogi state/kaduna governor

Ọjọ kọkanlelọ̀ọgbọn oṣu kini ọdun 2023 ni banki apapọ CBN kọkọ fi ṣe gbedeke paṣipaarọ owo beba olodindi igba naira (N200), ẹẹdẹgbẹta naira (N500) ati ẹgbẹrun kan naira (N1000) ki wọn to sun un siwaju si ọjọ kẹwaa oṣu keji ọdun 2023 lẹyin ti ọpọ ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni ke irora lori ilana eto naa.

Amọṣa awọn ipinlẹ mẹta kan, Kaduna, Kogi ati Zamfara gbe ijọba apapọ lọ si ile ẹjọ lori ọrọ naa, eyi lo mu ki igbimọ adajọ meje to n gbọ ẹjọ naa paṣẹ pe ki ijọba apapọ, banki apapọ CBN atawọn banki wọle gbowo- fowopamọ si gbogbo jami lori gbedeke ọjọ kẹwaa oṣu keji naa titi di igba ti ẹjọ ti wọn pe niwaju ile ẹjọ naa yoo fi ni iyanju.

Aworan Gomina banki CBN Godwin Emefiele ati owo beba tuntun

Aarẹ Buhari wa gba ọna miran yọ ninu ọrọ to ba awọn ọmọ Naijiria sọ lọjọbọ to kọja pe ki banki apapọ CBN o da owo beba igba naira (N200) olodindi pada si igboro fun nina di ọjọ kẹwaa oṣu kẹrin ọdun 2023. Buhari sọ ninu ọrọ naa pe ẹẹdẹgbẹta naira (N500) ati ẹgbẹrun kan (N1000) olodindi tẹlẹ ko ni jẹ nina mọ ni naira.

Ọpọ ero lawọn eeyan ti fihan lori ọrọ ti aarẹ sọ yii titi kan awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC ti aarẹ pẹlu wa.

Gomina Nasir El-Rufai (kaduna), Abubakar Badaru (Jigawa), Rotimi Akeredolu (Ondo), Umar Ganduje (Kano); olori ile igbimọ aṣojuṣofin, Fẹmi Gbajabiamila; minisita keji fun ọrọ awọn oṣiṣẹ, Festus Keyamo; atawọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn koju oro si aṣẹ ti aarẹ Buhari lori pe ẹjọ na naa ti wa niwaju ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria.