Àwọn oníṣẹ́ ibi ló ṣọṣẹ́ ni Sagamu, ohun tó bàjẹ́ pọ̀ ju tìgba Endsars lọ- Dapo Abiodun

Ìkọlù Banki ní Ṣagamu: Dapọ Abiọdun ṣe abẹwo s'awọn ibi t'awọn tọọgi ṣe ikọlu si
Gomina Dapọ Abiọdun ti ipinlẹ Ogun, ti ṣeleri wi pe gbogbo awọn olufẹhonuhan ati tọọgi to ṣe ikọlu s’awọn ile ifowopamọ ati ileeṣẹ mọnamọna n’igboro ilu Ṣagamu l’ọjọ Aje, ni a foju wina ofin.
Iṣẹlẹ yii Mọnde, ọsẹ yii.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ Aje, Mọnde to kọja yii ni wahala bẹ silẹ, nibi t’awọn eeyan ti n fẹhonuhan lori airi owo naira tuntun gba l’awọn ile ifowopamọ, paapaa awọn eyi to wa niluu Ṣagamu.
Nibi abẹwo naa ti kọmiṣónna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Frank Mba; Akarigbo ilẹ Rẹmọ, Ọba Babatunde Ajayi, atawọn kọmiṣọnna, to fi mọ awọn amugbalẹgbẹẹ ati oludamọran pataki ti kọwọrin pẹlu gomina, ni Dapọ Abiọdun ti kọminu lori ikọlu ọhun.
Dukia olowo iyebiye to jẹ t’awọn ile ifowopamọ ati nileeṣẹ panapana la gbọ pe awọn olufẹhonuhan bajẹ kọja sisọ.

Nigba to n sọrọ nibi abẹwo ọhun, Gomina Abiọdun sọ pe iyalẹnu nla lo jẹ f'oun wi pe awọn eeyan le ṣe ikọlu si banki, ti wọn yoo si ba ọpọ dukia jẹ.
O ni koda, wọn ko ba dukia to to bẹẹ jẹ lakoko ifehonuhan ENDSARS n’ipinlẹ.
"Mo wa sibi lati wo bi ikọlu ohun to ṣẹlẹ ni Ṣagamu lọjọ Aje, Mọnde ṣe le to.
Mo ti ṣabẹwo si ileeṣẹ panapana, ijọba ibilẹ, mo si tun wa loju ọna Akarigbo lati wo awọn ile ifowopamọ.
“Awọn ohun ti mo ri ba mi lọkan jẹ pupọ.
Mi o mọ ohun ti mo le sọ. Ifẹhonuhan lasan lo yẹ ko jẹ, ṣugbọn ohun ti mo ba pade yii, o fi han pe awọn amookunṣeka, oniṣẹ ibi lo ṣọṣẹ.
Awọn dukia ileeṣẹ panapana ati ileeṣẹ ijọba ibilẹ ti wọn bajẹ le ni obitibiti miliọnu naira.
L’awọn ile ifowopamọ gan-an paapaa, awọn tọọgi tun gbiyanjuu lati ji awọn ẹrọ kọmputa ati owo gbe salọ.

"Ifẹhonuhan yii ti kọja ilana owo ti wọn yi pada. A gbọ lati ẹnu awọn eeyan ti ọrọ ṣoju wọn, a si tun gbagbọ ninu ohun ti oju wa tun ri lonii, eyii si jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pupọ, paapaa bi idibo ṣe sunmọ etile.”
Dapọ ninu ọrọ rẹ tẹsiwaju pe oun nigbagbọ pe awọn tọọgi ti wọn n wa ọna lati da wahala silẹ lo lo anfaani ifẹhonuhan naa lati ṣiṣẹ buruku yii, to si ni pẹlu ohun to ṣẹlẹ yii, o ṣee ṣe ki idibo ba ma waye
O jẹ ko di mimọ pe awọn yoo ṣe iwadii lati rii pe ọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ si ikọlu naa, pẹlu ileri wi pe wọn yoo foju winna ofin, lati le fi wọn jofin.















