UN pàṣẹ fún Russia kó dáwọ́ ogun tó ń gbé ti Ukraine dúró, Russia ní kò jọ́

Russia Ukraine war

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ iṣọkan agbaye, UN General Assembly, ti fẹnukọ lati bu ẹnu atẹ lu bi orilẹ-ede Russia ṣe gbe ogun lọ ka Ukraine mọle.

Nibi ipade ajọ ọhun to waye niluu New York, UN ni awọn n fẹ ki Russia ko awọn ọmọ ogun rẹ kuro ni Ukraine, ko si fopin si ogun to n waye nibẹ.

Orilẹ-ede mọ́kànlélógóje, 141, lo ti fọwọ si pe ki ogun naa wa sopin, mejilelọgbọn sọ pe awọn ko fẹ da si ọrọ naa, nigba ti orilẹ-ede meje, eyii ti Russia wa lara wọn ni awọn n fẹ ki ogun ọhun ̣ṣi tẹsiwaju.

NI Vienna, ọpọ awọn aṣoju orilẹ-ede lo binu jade nibi ipade kan to waye nibẹ lasiko ti Russia n sọrọ lọwọ.

Ipade ajọ agbaye, UN ati ti Organization for Security and Co-operation in Europe, OSCE, ti awọn eeyan ti binu jade yii lo n waye ni bo ṣe ku ọjọ kan ki ogun ti Russia n gbe ti Ukraine pe ọdun kan.

Idibo UN naa pe fun alaafia ni kankan.

Wọn sọ nibi ipade naa pe orile¬̣-ede to da duro ni Ukraine, ko si tọ ki Russia maa dun mọhurumọhuru mọ ọ.

UN tun paṣẹ pe ki “Russia ko gbogbo awọn ọmọ ogun rẹ kuro ni Ukraine atawọn ilẹ to yi ka.”

Bo tilẹ jẹ pe ko si ofin to kin aṣẹ ti UN pa yii lẹyin, Russia gbọdọ tẹle fun anfani ara rẹ.

Lootọ ni pe ọpọ orilẹ-ede lagbaye lo pa aṣẹ naa, awọn orilẹ-ede mii to lẹnu nibẹ lagbaye ni ko da si aṣẹ ọhun.

Lara awọn orilẹ-ede ti ko kopa ninu idibo ti wọn fi paṣẹ naa ni China, India, Iran, South Africa atawọn orilẹ-ede mejidinlọgbọn mii.

Awọn orilẹ-ede meje to tako aṣẹ UN naa ni Russia, Belarus, North Korea, Eritrea, Mali, Nicaragua ati Syria.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ọdun 2022 ni Russia lọ gbe ogun ka Ukraine mọle.

Laarin ọdun kan naa ọpọ ẹmi lo ti sọnu, ti ọkẹ aimoye dukia si ti bajẹ.