Oja Odan killing: 'Accident' ọlọ́kàdá ló tú àṣírí àwọn afurasí méjì tí a bá orí eèyàn nínú àpò wọn- Oba Oyebamiji
Ọrọ awọn to n pa ẹlomii fi ṣoogun ọla ti n bi Ige ati Adubi ni Naijiria bayii.
Ilu Oja Odan ni ipinlẹ Ogun to wa guusu Iwo Oorun Naijiria ni BBC tun lọ bayii nibi ti awọn ara ilu ti binu dana sun awọn afurasi meji kan.Ìwádìí tó kúná ni a fẹ́ láti mọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́ olóògùn owó ní Oja Odan- Oba Oladiipo Oyebamiji
Wọn ni wọn ba ori eeyan kan to jẹ ọdọ ni ilu naa lọwọ awọn mejeeji ninu apo kan.
- Ẹ̀kún omi gbé èèyàn méjìdínlógójì lọ nílùú Petrópolis ní orílẹ́èdè Brazil
- Algeria yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní san N41,000 fáwọn ọ̀dọ́ tí kò rí iṣẹ́ ṣe lóṣù tó ń bọ̀
- EFCC gbẹ́sẹ̀lé dúkìá ọ̀gá olọgun tí iye rẹ̀ tó ₦10.9b
- 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'
- Ọjọ́ tí ọlọ́pàá mú mi kó mi láyà sókè, n kò le gbàgbé láéláé - Bad Boy Timz
- Wo ọkùnrin kan tó fi N1.2m gbẹ́ ibojì rẹ̀ sílẹ̀ nígbà tó sì wà láàyè

Kini Kabiesi Oja Odan sọ?
'Accident' ọlọ́kàdá ló tú àṣírí àwọn afurasí méjì tí a bá orí eèyàn nínú àpò wọn- Oba'
Awọn olugbe Oja Odan ṣalaye nkan to ṣẹle gangan fun BBC bi o ṣe jẹ pe ijamba ọkada naa ti ọkan ninu wọn ṣubu lo tu aṣiri wọn.
Koda, wọn ni pe awọn afurasi mejeeji naa ni pe wọn ṣetan lati fi milionu kan naira ṣe owo abẹtẹle ki wọn le fi wọn silẹ ṣugbọn awọn ọdọ kọ.
Kabiesi Oladiipo Oyebamiji naa salaye ohun to ṣẹlẹ ati igbesẹ ti ilu gbe nipa rẹ.
- Ààrẹ Mozambique tẹ́lẹ̀ rí jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n fi kan ọmọ rẹ̀
- Wo àwọn ewu àti ànfàní márùn ún tó wà nínú igbó mímu
- "Ó ṣeéṣe kí wọ́n ti ṣe àyípadà àti àtúnṣe sí fọ́nrán tí wọ́n gbé jáde lórí ọ̀rọ̀ Bàbá Ijesha"
- Yàtọ̀ sí Bimbo Success àti Kemi Korede, wo àwọn míì tí wọ́n ń pariwo Funke Akindele kiri
- Ìwádìí tó kúná ni a fẹ́ láti mọ̀ àwọn Onígbọ̀wọ́ olóògùn owó ní Oja Odan- Oba Oladiipo Oyebamiji
- Iléẹjọ́ tún sún ìgbẹ́jọ́ olórí ẹgbẹ́ IPOB Nnamdi Kanu síwájú
- Kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ láti yé da àlááfíà ìlú láàmú- Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun sí Aregbesola

Kini awọn agbofinro wa sọ si iṣẹlẹ naa?
Oga ọlọpaa Oyeyemi Abimbola to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣalaye pe nitooto ni iwa ibi naa ku diẹ kaa to ṣugbọn ẹnikẹni ko gbọdọ ṣe idajọ lọwọ ara rẹ.
O ni o yẹ ki awọn ero to dana sun awọn afurasi naa fun ọlọpaa laaye lati ṣe iwadii bi o ti yẹ ki iya to tọ si jẹ awọn Oniṣẹibi naa.
Ni ipari Oyeyemi ni pe ọwọ ọlọ́pàá ṣì máa tẹ̀ gbogbo àwọn èrò tó kópa nínú dídáná sun awọn afurasí náà.
O ni o ṣeeṣẹ ki awọn eeyan lo maa ta ẹjẹ alaiṣẹ silẹ ti wọn ba n sun eeyan bayii.




