Ukraine President: Zelensky jẹ ààrẹ, ọ̀pọ̀ adẹ́ẹ̀rínpòṣónú Nàìjíríà kún ojú òṣùwọ́n jú àwọn adarí wa lọ

Oríṣun àwòrán, Gbenga Adeyinka/instagram
Agba ọjẹ adẹrinpoṣonu l'orilẹede Naijriia, Gbenga Adeyinka , ti sọ pe pupọ ninu awọn adẹrinpoṣonu ni Naijiria lo ni imọ, to si koju oṣuwọn lati di ipo oṣelu mu.
O sọ eyi ni ifesi si bi adẹẹrinpoṣonu kan, Volodymyr Zelensky ṣe di aarẹ orilẹede Ukraine.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gbenga Adeyinka sọ pe ọpọ awọn adẹrinpoṣonu ni Naijiria lo kawe ju awọn to n dari wa ni Naijriia, ti wọn si ni imọran, erongba ati ọgbọ́n to le gbe Naijiria ga.
O ni aye igba kan ni awọn adẹẹrinpoṣonu jẹ alagbe, ti wọn si kawe.
Adeyinka ni ara afojusun oun gẹgẹ bi ẹnikan ni lati di ipo oṣelu mu lọjọ iwaju.
Lọjọ Aje ni wọn bura sipo fun aderinposonu ọmọ orileede Ukrain,Volodymyr Zelensky, gẹgẹ bi aarẹ ilẹ naa tuntun.
Ọgbẹni Zelenskyti ko ni iriri kankan tẹlẹ lagbọ oṣelu lo jawe olu bori ninu idibo aarẹ to waye ni Ukraine loṣu to kọja.

Oríṣun àwòrán, AFP
O yẹ aga nidi aarẹ Petro Poroshenko to ti wa lori aleefa lati ọdun 2014.
Zelensky ti ṣe ileri lati koju iwa ajẹbanu ati pe oun yoo mu opin ba ogun to n waye laarin orileede naa ati awọn ọmọ ogun ọlọtẹ lariwa orileede ọhun ti Russia n gbe lẹyin wọn.
Ko tii daju awọn ọrọ ti yoo mẹnu ba ninu ọrọ rẹ akọkọ gẹgẹ bi aarẹ. Lati igba ti o ti jawe olubori ninu idibo, niṣe ni o mẹnumọ.
Wọn ti n ṣe fakinfa lori ọjọ ati asiko ti iburawọle yi yo waye. Zelensky fẹ ṣe ni ọjọ Aiku ọjọ to jẹ ayajọ idaro awọn to ku lasiko ijọba Stalin lorileede naa.
Amọ ile aṣofin tako ti wọn si dibo pe ki o waye lowurọ ọjọ Aje.

Oríṣun àwòrán, AFP
Bi ere bi ere,ọrọ naa di ododo
Voldymyr Zelensky ti ṣe aarẹ ri botilẹ jẹ wipe ninu ere ori amohunmaworan to ti ṣe bi aarẹ Ukrain.
Ninu ere naa ọkọ akero tansi lo wọ de ibi iburasipo rẹ ti o si kọ lati ṣe ileri to gbongbon. Dipo eyi, o pinu lati sapa fawọn eeyan orileede Ukraine.
Lọjọ Aje yoo ṣelẹ gan loju aye, o si le ma yatọ si bi o ti ṣe waye ninu ere amounmaworan naa, a o le sọ.
Ọgbẹni Zelensky ko ni wọ ọkọ akero wa sibi ayẹyẹ ibura rẹ ṣugbọn o ti saaju fi fọnran fidio kan sita loju opo ayelujara pe oun tọrọ aforijin lọdọ ara ilu nitori sunkere fakẹrẹ ti ayẹyẹ naa yoo da silẹ.













