Local Government Autonomy: Ìgbésẹ̀ àjọ NFUI kò bá òfin mu rárá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Onimọ nipa ofin, Deji Olabiwọnnu ni igbesẹ ajọ NFIU lati fofin de ijọba ipinlẹ pe ki wọn ma tọwọ bọ owo ijọba ibilẹ mọ ko tọna ṣùgbọ́n lootọ, odun to dara ni wọn ṣe.
Deji sọ wi pe ko si ohunkohun ti ẹnikẹni ba n ṣe, ti ko ba ti ba ofin mu, ko tọna.
Laipẹ yii ni awọn alaga ijọba ibilẹ n gbosuba kare fun ilana tuntun ti ileeṣẹ ijọba to n mojuto eto isuna National Financial Intelligence Unit, NFIU gbe kalẹ lati fun ijọba ibilẹ lagbara.
Ninu ilana tuntun naa, wọn sọ pe wọn ko ni le lo owo to ba yẹ ki wọn fun awọn ijọba ibilẹ ninu akoto owo apapọ pẹlu ijọba ipinlẹ fun nnkan miiran.
Bẹrẹ lati ọjọ kini oṣu Kẹfa, ijọba ibilẹ yoo ma gba owo wọn lọtọ ti ijọba ipinlẹ ko si ni le ma la lewọn lọwọ lori owo naa.
Onimọ nipa ofin jẹ ko di mimọ pe bakan meji ni ọ̀rọ̀ naa. Ni ida kinni, o ni "igesẹ ti ajọ yẹn gbe dara fun ẹni ti ko ba fẹran iwa jẹgudujẹra ṣugbọn ko si bi igbesẹ naa ṣe fẹ dara to, ti ko ba ti ba ofin mu, ko dara naa niyẹn.
O ni iwe ofin Naijiria, abala 162 lo sọ pe apo ifowo pamọ si kan yoo wa fun ijọba ipinlẹ ati ibilẹ ninu eyi ti owo to ba n wa lati ọdọ ijọba apapọ ati ti ipinlẹ si ijọba ibilẹ yoo maa lọ sinu rẹ.
Ṣugbọn ofin ti ajọ NFIU wa gbe silẹ sọ wi pe "gbogbo owo yii ko maa lọ si apo ijọba ibilẹ kọọkan taara lati ọwọ ijọba apapọ eyi to lodi si ofin ijọba apapọ".
Eyi ni ajọ gomina n fapa janu fun. Ẹwẹ ni tiwọn naa, amofin Deji ni lootọ ki ale gba iwa jẹgudujẹra tabi ṣiṣe owo ilu danu lawujọ, o dara ki ijọba ibilẹ da wa kuro labẹ akoso ijọba ipinlẹ patapata.
Nitori naa, Deji ni ofin lo gbudọ maa bori ninu ohun gbogbo. Kaka bẹẹ o ni ki awọn tọrọ kan kọkọ ṣe atunṣe ofin to ni ṣe pẹlu gbigbogun ti iwa jẹgudujẹra na, ki wọn wa gbe igbesẹ lati pa ofin naa ki wọn lee ri ofin ti i lẹyin.













