Olubadan of Ibadan: Olóye Ọ̀tún ní ìjà ti parí ṣùgbọ́n àwa ò gbé adé sílẹ̀ o!

Àkọlé fídíò, Imperial Majesty ni Olubadadan, Royal Majesty làwa, òfin sì tẹ̀lé e - Ọtun Olubadan

Laipẹ ni iroyin kan pe awọn Ọba tuntun ti gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Ajimobi fi jẹ ọba ti pari aawọ to wa laarin wọn àti Olubadan, Oba Saliu Adetunji.

Lori eleyii, Kabiyesi Saliu Adetunji ti ṣaaju fi ọrọ lelẹ pé bi wọn ba fẹ ma wọ afin oun gẹgẹ bii Olubadan, wọn gbudọ gbe ade wọn silẹ.

Ẹwẹ, awọn oloye naa fi ọrọ̀ sita lootọ, awọn ti pari ija ṣugbọn kii ṣe bii ti ki awọn wa bọ ade ori awọn silẹ gẹgẹ bii ọba.

Ọtun Olubadan, Olóyè Leka Balogun ni "ohun ti sẹnetọ Ajimobi ṣe yii gan lo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jẹ́ titẹle aṣa ilẹ Yoruba.