Olubadan: Ọjọ́ Kọkànlá oṣù Kẹta ní lekan Balogun yóò gba adé bíi ọba Ibadan

Agba Oy Lekan Balogun, Olubadan ilẹ Ibadan tuntun

Ijọba ipinlẹ Ọyọ kede ọjọ ti Olubadan tuntun yoo gun ori itẹ.

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti fi ontẹ lu ọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun yii fun iyansipo Sẹnetọ Lekan Balogun gẹgẹ bi i Olubadan ti ilẹ Ibadan ikejilelogoji.

Atẹjade ti akọwe agba fun ileeṣẹ ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Bashir Olanrewaju buwọlu, eyi ti wọn kọ ranṣẹ si Sẹnetọ Lekan Balogun, lo sisọ loju ọrọ naa.

Atẹjade ọhun ni akọri rẹ n jẹ "Ayẹyẹ Ifinijoye: Olubadan ilẹ Ibadan" lo fi idi aṣẹ gomina mulẹ lori igbesẹ naa.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Iwe naa ka bayii:

"Mo fẹ lati tọka si iwe kan to ni itọka 'No.18SELG.243TI/17' ti ọjọ kẹrindinlogun oṣu keji ọdun 2022 wa lori rẹ.

Akọle to n bẹ loke yii ati lati fi to ọ leti pe Ọlọlajulọ Gomina ipinlẹ Ọyọ ti fi ontẹ lu ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun 2022 gẹgẹ bi i ọjọ ti Olubadan tuntun yoo gba ade.

Lẹẹkan si i, ẹ ku oriire Kabiyesi."

Saaju ni Gomina Makinde buwọlu iyansipo Balogun gẹgẹ bii Olubadan tuntun lọjọ kẹrinla oṣu keji.

Igbesẹ naa si lo waye lẹyin ti igbimọ Olubadan ti ilẹ Ibadan, fi orukọ rẹ ṣọwọ si Gomina ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bi i ẹni ti o kan lati jẹ oye naa.

Iyansipo yii si n waye lẹyin ipapoda Olubadan ana, Ọba Saliu Adetunji.

Àkọlé fídíò, Imperial Majesty ni Olubadadan, Royal Majesty làwa, òfin sì tẹ̀lé e - Ọtun Olubadan