NFF kò ti san owó tó jẹ Super Falcons ní Morocco títí di àsìkò yìí

Awọn agbabọọlu Super Falcons

Oríṣun àwòrán, Super Falcons

Ẹgbẹ agbabọọlu obinrin orilẹ-ede Naijiria ko tii ri owo ti ajọ bọọlu alafẹsẹgba ni Naijiria, ati ileeṣẹ ere idayara, jẹ wọn fun idije ife awọn obinrin ni Africa, WAFCON, to waye loṣu to kọja.

Ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons kọ lati lọ si papa iṣere fun igbaradi wọn fun ifẹsẹwọnsẹ ti wọn fi koju Zambia lọjọ kejilelogun, oṣu Keje, nitori pe wọn jẹ wọn ni owo ajẹmọnu.

Ifẹsẹwọnsẹ naa lo sọ ẹni to ṣe ipo kẹta.

Owo to le ni ẹgbẹrun mẹwaa Dọla, ni wọn jẹ ẹnikọọkan awọn agbabọọlu naa, lara eyi ti ajẹmọnu wọn fun bibori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta to mu wọn wọ ipele semi finals ni idije WAFCON.

Botilẹ jẹ pe ajọ NFF sọ pe oun yoo san owo naa laipẹ, ẹnikan lara awọn agbabọọlu naa sọ fun BBC Sport Africa pe oriṣiriṣi irọ̀ ni wọn n pa fun awọn.

“Wọn kọkọ sọ fun wa lọjọ ti a da iṣẹ silẹ ṣaaju ọjọ ti a koju Zambia pe, wọn ti buwọlu owo naa, ti awọn yoo si san laipẹ.”

O ni lati igba naa ni wọn ti pa irọ bii pe awọn nọmba apo asunwọn ti awọn agbabọọlu fun ko pe, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

BBC Sport Africa kan si ajọ NFF ati ileeṣẹ ere idaraya lori ẹsun naa.

Ẹnikan lara awọn olori ajọ naa sọ fun BBC lọjọru pe o yẹ ki awọn agbabọọlu naa ri owo wọn gba lọsẹ yii, nitori pe awọn ti ṣiṣẹ lori rẹ.

Wọn ti san apapọ $2,800 ni owo ti awọn agbabọọlu naa n na lojoojumọ ati ajẹmọnu fun awọn nkan mii ṣaaju idije WAFCON fun wọn.

Awọn owo ti wọn ko tii ri gba ni awọn ajẹmọnu wọn fun WAFCON, ati fun awọn irinajo wọn si Austria ati Canada, to fi mọ eyi ti wọn fi lu Ivory Coast ṣaaju idije WAFCON.

Igba akọkọ kọ re e ti ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons fẹhonu han lori owo ti ijọba jẹ wọn.

Wọn ti ṣe bẹẹ ri ni idije WAFCON meji to ti waye ri, ni South Africa lọdun 2004, ati ni Abuja lọdun 2016.