''Láélaé! Naijiria kọ́ ló kàn láti gbàlejò Afrcia Cup of Nations ti 2025''

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Adari Ajọ Elerebọọlu ni Naijiria, Amaju Pinnick ti sọ pe Ajọ elereebọlu ilẹ Afrika ti ni orilẹede Naijiria ko lee gbalejo idije African Cup of Nations ni ọdun 2025.

Pinnick fi eyi lede ni ọjọ Iṣẹgun pe igbiyanju wọn lati gbalejo idije Afcon 2025 ti bọ si pabo.

O ni Ajọ Caf ni orilẹede Guinea ni awọn ti gbe igbalejo naa fun un, ti ko si si ohun to tii yipada.

Ohun ti Naijria n fẹ ni lati jijọ gbalejo idije naa pẹlu orilẹede Benin Republic paapaa aṣekagba idije naa.

Saaju AFCON 2025, Ijọba Ologun ni o n dari Guinea lọ́wọ́lọ́wọ́

Orilẹede Guinea ti wọn gbe idije naa fun lo n koju ijọba ologun lọwọlọwọ lẹyin ti ikọ ologun lorilẹede naa gba iṣakoso ni ọdun to kọja.

Eyi ti fa ki awọn eniyan ma a bẹru nipa eto aabo lorilẹede naa lasiko idije Afcon naa ni ọdun 2025.

Amo ọkan lara awọn ọga agba Caf to ba awọn oniroyin sọrọ ni ko si ohun to ti yipada nitori Guinea ni akọsilẹ wa pe yoo gbalejo idije naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọdun 2019 ni orilẹede Guinea gba lati gbalejo idije Afcon 2025 lẹyin ti Ajọ Caf naa ṣe agbeyẹwo idije Afcon fun ọdun 2019, 2021 ati ọdun 2023.

Nibayii, idije to yẹ ko waye ni ọdun 2023 ni wọn ti gbe lọ si ọdun 2024 nitori asiko oojo.

Bakan naa ni Naijiria to n gbiyanju lati gbalejo ti ọdun 2025 naa n koju eto aabo to dẹnukọlẹ, ti ko si agbegbe ti aabo to ye kooro wa.