Àfi kí ẹkùn kọ́ọ̀kàn wà ojútùú sí ipenija ààbò fún ará wọn - Gani Adams

aworan gani adams

Oríṣun àwòrán, others

Aarẹ Onakakanfo ilẹ Yoruba Iba Gani Adams ti kesi ìjọba àpapọ lati wa ojutu sí ipenija ààbò nípa didari ona abayọ sí ẹkun kọọkan lorileede Naijira.

Adams fìdí ọrọ yi múlẹ lasiko to gbalejo ìkọ ẹgbẹ idagbasoke Yoruba kan torukọ wọn n jẹ Voice of Reason (VOR).

Aarẹ ọna Kakanfo ni orileede Naijiria ti kùnà láti pese aabo fawọn araalu pẹlu b'awọn kọlọrọsi eeyan kan ti n dunkoko mọ ọmọ Naijiria.

Gani Adams ko ṣe àlàyé pato bi aba to muwa yi yoo ti ṣe di imusẹ ṣugbọn o ni igbesẹ tàwọn ìjọba ìpínlẹ̀ ilẹ kaarọ o jiire ti gbe nipa idasilẹ Amọtẹkun ko buru.

O ni òun mọ pé awọn ìkọ Amọtẹkun naa yóò ṣe iṣẹ bi o ti yẹ lati pese aabo nigba to ba di dandan.

Ninu esi rẹ alaga ìkọ VOR Olusola Adekanola sọ pé àwọn ṣe ipade pẹlu Aarẹ Ọna Kakanfo lati le wá ọnà abayọ sí ipenija aabo to n koju ilẹ Yoruba.

Bakan naa lóun naa so pe ìjọba ẹlẹkunjẹkun jẹ ọnà kan gbòógì ti awọn fi lè doju kọ ipenija aabo kaakiri Naijiria.

Ni ilẹ Yoruba ati láwọn ọpọ ibi jakejado Naijiria ipenija ààbò jẹ eleyii to n kọ t'onile t'alejo lominu.