Russian Lesbian advert: Ìpólówó ọjà wo ni Iléeṣẹ́ oloúnjẹ Russia yi ṣé tó dá rugudusílẹ̀

Afihan ipolowo akọkọ ti ileeṣẹ VkusVill gbe sita

Oríṣun àwòrán, vkusvill.ru

Àkọlé àwòrán, Aworan to da awuyewuye si ree loju opo ileese VkusVill

Awọn eeyan lorileede Russia ti n fi ero ọkan wọn han lori bi ileeṣẹ kan to n ta ounjẹ alagolo ṣe fi ipolowo ọja pẹlu idile abo si abo kan sita ti wọn tun pada yọ ọ kuro.

Niṣe ni ipolowo yi mu inu bi awọn to lodi si ati awọn to nifẹ rẹ bakan naa nitori wọn fa a yọ kuro loju opo ayelujara.

Loju opo ileeṣẹ VkusVill ni wọn fi ipolowo yii si. Ileeṣẹ naa sọ pe awọn ti ọjọ ori wọn kọja ọdun mejidinlogun lawọn ṣe e fun.

Àkọlé fídíò, Bisi Alimi: Ìyà mi rò pé n kò leè ṣe ni àmọ́ n kò ní ìfẹ́ abo ni mo ṣe fẹ́ akọ

Ni Russia, wọn fofin de eyikeyi ipolowo ọja to baa n ṣafihan iwa akọ si akọ tabi abo si abo laarin awọn ọmọ ti ko ti balaga.

Yatọ si eyi, ofin kan to wa nilẹ naa lati ọdun 2013 fofin de igbeyawọ akọ tabi abo si abo to fi mọ ki wn lawọn fẹ gba ọmọ tọ

Kaka ki aworan yi ṣafihan baba, iya ati awọn ọmọ,awọn obinrin lo duro bi iya ati baba pẹlu awọn ọmọ ninu aworan ipolowo yi.

VkusVill ti wọn pe ileeṣẹ naa tun mọ si "Tasteville" lede gẹẹsi.

Afihan ipolowo tuntun ti ileeṣẹ VkusVill gbe sita

Oríṣun àwòrán, vkusvill.ru

Àkọlé àwòrán, Aworan ti wọn fi parọ alakọkọ

Ileeṣẹ naa ti tọrọ aforijin loju opo Instagram wọn plu aworan to sọ pe''A fi apilẹkọ kan sita nibi ti ko dun mọ ọpọ awọn alabara wa,oṣiṣẹ ati awọn alabaṣe.A banujẹ lori iṣẹlẹ a si gba pe awa la lẹbi iṣẹlẹ naa,eyi to fi han pe awọn oṣiṣẹ wa kan ko ṣiṣẹ wn boṣe yẹ''

Lẹyin ti wọn yọ aworan yi awọn eeyan fi ọrọ ranṣẹ si wọn.

Gbajumọ oju opo ayelujara kan Ksenia Sobchak sọ loju opo Instagram pe ''Se wọn ro pe awọn eeyan ko ni ra ọja wọn nitori ipolowo ti wọn fi idile abo si abo ṣe?Ko ṣeeṣe.Ni bayi ati awn to faramọ iru iṣesi yi ati awọn to tako lo ti n binu si wọn''

"Will people really boycott curd snacks and cherries because of lesbians? Of course not... But now both sides hate the retailer," said prominent social influencer Ksenia Sobchak on Instagram.

Akọrin Mozee Montana ni "Idojuti nla leyi jẹ. Wọn tabuku ara wọn"