Sunday Igboho: YWG ní káwọn àgbà Yorùbá báwọn ajìjàgbara sọ̀rọ̀ láti dẹkun ìpè fún ìyapa

Ẹgbẹ Yoruba Welfare Group (YWG), ti kesi awọn ọba alaye atawọn asaaju oloselu nilẹ Yoruba lati dide doola aawọ to n waye laarin Sunday Igboho ati eyi to fi n da si ijọba apapọ.
Ẹgbẹ YWG lọgun bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita eyi ti aarẹ ẹgbẹ, Comrade Abdulhakeem Adegoke Alawuje fọwọsi to da lori bi DSS se kọlu ile ajijagbara naa ati bi ijọba apapọ se kede pe oun n wa Sunday Igboho.
Ẹgbẹ naa wa rọ ijọba apapọ lati jẹ ki awọn agbaagba nilẹ Yoruba ba Sunday Igboho atawọn ọmọlẹyin rẹ sọrọ lọna ati jẹ ki alaafia jọ̀ba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo ti yọ'wọ́ lọ́rọ̀ òṣèlú Nàìjíríà, tẹ́ẹ bá ń gbọ́ pé Obasanjo dá ẹgbẹ́ òṣèlú sílẹ̀, "ẹyẹ mi kọ́"!
- Sunday Igboho kò ṣẹ̀ s‘ófin, ẹ dẹ́kun ọ̀nà láti mu - Agbekoya
- Ẹ fi Sunday Ìgbòho sílẹ, ǹkan tí ìjọba Nàìjíríà bàjẹ́ ló ń gbìyànjú àti túnṣé; Ìjọba àpapọ̀ ní láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀ - Wole Soyinka
- Bí wọ́n ṣe n ṣe ètò ìsìnkú T. B Joshua l‘Eko, làwa nàá yóò ń ṣe ní Arigidi - Zaki ìlú Arigidi
- Ẹ tẹ̀síwájú pẹ̀lú ètò ìsínkù Wòlí TB Joshua, àyẹ̀wò ṣọ́ọ̀ṣì yín tí a ṣe dáńgájíá- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko
- Ó tún ti ṣẹlẹ̀! Agbébọn tún jí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Baptist kan gbé
- Àwọn ọmọ ìkókó níléèwòsàn kàgbákò agbébọn! Wọ́n jí wọn gbé pẹ̀lú nọ́ọ̀sì
- Àwọn gómìnà ní Gúúsù Naijiria ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko
O ni eyi yoo tun fun wọn lanfaani lati dẹkun idunkooko lati da ilu ru nipa bi wọn se n pe fun ominira ilẹ Yoruba kuro lara Naijiria.
"A n rọ awọn eekanlu nilẹ Yoruba lati gbe ọrọ ẹsin tabi oselu ti sẹgbẹ kan, ki wọn si fori jin Sunday Igboho lori awọn ẹsẹ to le sẹ wọn.
Amọ ki wọn dide lati gba oun atawọn alatilẹyin rẹ lọwọ awọn ẹsun ti ijọba apapọ fi kan wọn nitori alaafia ilẹ Yoruba se koko.
Gẹgẹ bii ajogunba wa, Ololufẹ alaafia ni awa ọmọ Yoruba, a ko si le kuna ninu ojuse yii, paapaa lori ọrọ to nii se pẹ́lu ilẹ baba nla wa."
YWG ni oun le fi ọwọ sọya pe ẹya Yoruba ko fara mọ iyapa Naijiria, to si n fẹ orilẹede to wa ni isọkan ati alaafia nibi ti idajọ ododo, ibaradọgba, aisegbe sibikan ati isejọba rere yoo ti wa.
Ẹgbẹ naa wa n fi ọwọ sọya pe oun yoo maa kan si awọn asaaju nilẹ Yoruba lati da si ọrọ to wa nilẹ yii, ki wọn si jẹ ki alaafia jọba nilẹ Yoruba.


















