Sunday Igboho: Àpapọ̀ gómínà ilé Yoruba fòfin de kí ọlọ́pàá, sójà, DSS dédé wọ ìpínlẹ̀ wọn

Awọn gomina

Oríṣun àwòrán, Instagram/rotimi akeredolu

Awọn gomina ni ẹkun Gusu Naijiria ti panupọ sọpe o ti di eewọ fun awọn ẹṣọ agbofinro ati ẹṣọ alaabo lati wa ṣiṣẹ kankan ni ilẹ Yoruba lai gba aṣẹ lọwọ wọn.

Awọn gomina yii lo sọ bẹẹ nibi ijiroro to waye ni ilu Eko pẹlu awọn Gomina to wa ni Guusu Naijiria.

Awọn gomina naa ni awọn ẹṣọ alaabo ni aṣẹ lati fi to awọn leti nitori awọn ni adari ẹsọ awọn alaabo nipinlẹ.

Àkọlé fídíò, BBC Yoruba pada lọ ṣabẹwo si ọja Bode nibi ti ọkọ to kun fọọ fun afẹfẹ gaasi ti dede sina wọ inu ọja to si pa awọn kan.

A ti pe nkankan ko gbọdọ maa ṣẹlẹ ni agbegbe wọn ki wọn ma mọ nipa rẹ.

Atẹjade awọn gomina naa ko darukọ iṣẹlẹ ikọlu ti ikọ awọn agbofinro sẹ ni ilu Ibadan si ile ajijagbara Sunday Igboho.

Govnor Rotimi Akeredolu

Oríṣun àwòrán, Govnor Rotimi Akeredolu

Amọ, awọn eniyan lero wi pe iṣẹlẹ ikọlu naa lo mu ki awọn gomina naa gbe iru igbesẹ bẹẹ.

Àwọn gómìnà ní Gúúsù Naijiria ń ṣe ìpàdé lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko

Awọn gomina lati awọn ipinlẹ to wa ni Guusu Naijiria ti sẹ ipade nipinlẹ Eko.

Gomina ni ilẹ Yoruba

Oríṣun àwòrán, Akeredolu/Facebook

Nibi ipade naa ti gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, dari, lo waye ni ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to wa ni Alausa, Ikeja.

Yatọ si Akeredolu, gomina mẹẹdogun mii lo tun wa nibi ipade naa.

Awọn gomina

Oríṣun àwòrán, Instagram/rotimi akeredolu

Lara wọn lati ri Babajide Sanwo-Olu ti Eko, Kayode Fayemi lati Ekiti, Gboyega Oyetola lati Osun, Nyesom Wike lati Rivers, Seyi Makinde lati Oyo, ati awọn mii.

Gomina Akeredolu to ba awọn akọroyin sọrọ ki ipade ti wọn ti ilẹkun mọri ṣe ọhun to o bẹrẹ, sọ pe awọn yoo sọ nkan ti ipade naa da le lori lẹyin ti awọn ba pari.

Àkọlé fídíò, 'Oko ni mo wà lọ́nà "Express" Ilesha tí àwọn agbébọn yìnbọn bá ẹnu mi tí mò fi dà báyìí'