Ex-Jamb Registrar Ojerinde: Iléẹjọ́ tàpá sí gbígba béèlì Ojerinde adájọ ní kó padà sí àhámọ́

Oríṣun àwòrán, Jamb
Ile ẹjọ giga kan ni olu ilu Naijiria, Abuja ti kọ lati gba beeli ọga ajọ to n ri si idanwo aṣewọle ẹkọ giga, JAMB tẹlẹ ri Dibu Ojerinde.
Ẹsun ajẹbanu ni Ojerinde n kawọ pọnyi rojọ le lori eleyi ti ajọ to n risi iwa ajẹbanu awọn oṣiṣẹ ijọba ICPC fi kan an.
Adajọ Obiora Egwuatu gẹgẹ bi iroyin to tẹwa lọwọ ni o kọ iwe gbigba oniduro Ojerinde ti agbẹjọro rẹ P.O Olorunishola mu wa siwaju ile ẹjọ.
Agbẹjọro ICPC Ebenezer lo tako gbigba oniduro rẹ ninu ẹsun onipele mejidinlogun.
Ọjẹrinde to wọ aṣọ funfun wa si ile ẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Ọga ajọ to n mojuto idanwo igbaniwọle awọn akẹkọọ to fẹ wọ fasiti ni Naijiria(JAMB) yi ni wọn fẹsun kan pe o ṣe owo biliọnu marun un le diẹ kumọ kumọ.
Adajọ ni ki wọn ṣi fi Ojerinde si ahamọ lọdọ ileeṣẹ ẹlẹwọn titi di igba ti wọn yoo tun gbẹjọ rẹ.








