Sunday Igboho: Ladoja ní bí ìjọba kò bá fi ẹ̀lẹ̀ ṣe, ọ̀pọ̀ ajìjàgbara míì yóò dìde
Gomina tẹlẹri nipinlẹ Oyo, Sẹnetọ Rasidi Adewolu Ladoja ti sọ wi pe, ijọba apapọ lo da awọn ajijagbara bii Sunday Igboho, to n ja fun ilẹ Yoruba ati Nnamdi Kanu to n ja fun idasilẹ orilẹede Biafra silẹ.
Ladoja lo sọ bẹẹ ni ile rẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to gbadura Ileya tan ni ọjọ Iṣẹgun.
O ni ijọba apapọ to kọ lati koju awọn ipenija ijinigbe, ipaniyan awọn araalu kaakiri orilẹede Naijiria, paapaa ilẹ Yoruba lo mu awọn eniyan bi Sunday Igboho di adari fun awọn eniyan rẹ.
Gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ wa parọwa si ijọba apapọ lati ṣe pẹlẹpẹlẹ pẹlu bi wọn ṣe fi panpẹ ọba mu Sunday Igboho nitori ọpọlọpọ eniyan bii Sunday Igboho ni yoo dide ti ijọba ba fi ọwọ agbara mu awọn ti wọn mu yii.