Wo ìlú tí wọ́n ti fòfin dé yíya àwòrán ṣaájú ìgbéyàwó ìyẹn "pre wedding picture" àti ètò ìgbéyàwó mìíràn

Iyawo tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iyawo tuntun

Báyìí là ń ṣe nílé wa èèwọ̀ ilẹ̀ ibòmíràn.

Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn Islam ní ìjọba ìbílẹ̀ Mayo Belwa ní ìpínlẹ̀ Adamawa ní àwọn ti fòfin de ṣíṣe àwọn ayẹyẹ kan ṣaájú àti lẹ́yìn ìgbéyàwó kí ìbágbépọ̀ tọkọtaya lé rọrùn si.

Gẹ́gẹ́ bí àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ yìí ṣíṣe ayẹyẹ patí "Cocktail", ọjọ́ abúlé (Village Day), Luncheon, àyájọ́ Fulani (Fulani day), àti Budar Kai ti di èèwọ̀ níbi ayẹyẹ ìgbéyàwó.

Láti àsìkò yìí lọ, tí òfin náà bá fi ẹsẹ̀ rinlẹ̀, ṣíṣe àmúlò orin níbi ètò ìgbẹyàwó yóò di ohun ìgbàgbé.

Kini Igbimọ naa fi sita?

Abẹnugan ìgbìmọ̀ náà, Ahmadu Liman Aminu ní àwọn gbe ìgbésẹ̀ yìí láti mú kí ètò ìgbéyàwó rọrùn fún àwọn ọ̀dọ̀ tó ń gbèrò láti ṣe ìgbéyàwó.

Àkọlé fídíò, Bad Boy Timz: Fásitì ni mo wà tí mo fi kọrin ‘Gbẹ́sẹ̀ lọ́kọ̀ọ́ọ̀kan’ tó sọ mi di gbajúmọ̀

Nígbà tó ń ṣàlàyé fún BBC Hausa ìdí tí àwọn fi gbé ìgbésẹ̀ náà, Ahmadu ní nítorí à ti mú àdínkù bá iye owó tí àwọn ènìyàn ń ná lórí ìgbéyàwó lásìkò yìí pẹ̀lú bí nǹkan kò ṣe fararọ ní orílẹ̀ èdè wa ló fà á tí àwọn fi ṣe òfin náà.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe: Àwọn ọmọde tí mò ń bá ṣe ‘skit’ ló dáwó jọ fún mi nígbà tí àìsàn inú dé sí mi

Bákan náà ló ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ̀ ni kò fẹ́ ṣe ìgbéyàwó mọ́ nítorí owó gege tí wọ́n ń ná láti fi ṣe ìgbéyàwó à ti pé ọ̀pọ̀ àṣà àti ìṣe ni wọ́n ń tẹ̀ lójú mọ́lẹ̀, èyí tó fàá tí àwọn ọmọdé kò ní ẹ̀kọ́ tó bẹ́ẹ̀ mọ́.

Ọ̀nà wo ní wọ́n fẹ́ gbà láti fi fi òfin náà múlẹ̀?

Ahmadu ní pé ẹni tí ó bá kọtí ọ̀gbọin sí òfi tuntun yìí, àwọn yóò kọ̀ọ́ tì nínú ìlú, tí àwọn kò ní dá sí gbogbo ayẹyẹ tó bá ń ṣe ìbáà jẹ́ ìgbéyàwó tàbí ìkómọ.

Ó ní kódà bí ẹni náà bá kú, àwọn kò ní yọjú síbi ètò ìsìnkú ẹni náà.

Àkọlé fídíò, Damilọla pàdánù ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nítorí ilà kíkọ

Àwọn ìgbésẹ̀ mìíràn tí wọ́n tún gbé

Ìgbìmọ̀ náà tún ní àpótí tí àwọn ẹbí máa ń gbà lásìkò ayẹyẹ ìgbéyàwó kò gbọdọ̀ ju méjì lọ báyìí mọ́ tí àwọn nǹkan tí wọ́n yóò kó sínú rẹ̀ jẹ́ aṣọ ìró méje, bàtà mẹ́ta, gèlè mẹ́ta, hìjáàbù mẹ́ta, yẹtí mẹ́ta àti ẹ̀gbà ọwọ́ àti tọrùn mẹ́ta mẹ́ta.

Àkọlé fídíò, OAU student's death: O dun OAU pé Heritage kú, agbìyànjú láti gbé e délé ìwòsàn ṣùgbọ́n...

Bákan náà ni wọ́n ó ti di èèwọ̀ láti máa gba owó lọ́wọ́ ọkọ tàbí ẹbí rẹ̀ yàtọ̀ sí owó orí.

Wọ́n tún ṣe àjọ tí yóò máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn tó bá fẹ́ ṣe ìgbéyàwó.

Àkọlé fídíò, 'Ìyá Tíṣà lòdì sí kí n mutí, fagbó tàbí sìgá'

Kí ni èrò àwọn ará ìlú?

Nígbà tí akọ̀ròyìn BBC, Salihu Adamu bá àwọn tó ń gbèrò láti ṣègbéyàwó lópin ọ̀sẹ̀ yìí láti sọ ohun tí wọ́n rò lórí ìgbésẹ̀ ìgbìmọ̀ náà, wọ́n ní àwọn faramọ́.

Àkọlé fídíò, Agbẹdẹ Adodo

Lára àwọn tó sọ̀rọ̀ ní pé nígbà tí èèyàn bá fẹ́ ṣe patí ṣùgbọ́n tí owó tí yóò fi pe eléré ti pọ̀jù láìsí ní owó lọ́wọ́ kìí ṣe ohun tó dára tó.

Wọ́n ní àwọn faramọ́ ìgbésẹ̀ yìí àti pé gbogbo àwọn àwòrán náà kò wúlò.

Àkọlé fídíò, 'Ǹkan tó jẹ́ kí iṣẹ́ ọ̀nà tèmi yàtọ̀ lágbàáyé ni ǹkan tí mò ń lò'