Obasanjọ's Birthday: Nàìjíríà yóò túbọ̀ máa wojú ààrẹ àná Olusegun Obasanjo fún ẹkọ́, ọgbọ́n àti ìmọ̀ láti tukọ̀ orílẹ̀-èdè yìí- Buhari

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ààrẹ Muhammadu Buhari ni yóò túbọ maa wo ojú ààré àná lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà Olusegun Obasanjo fún ọgbọ́n ìmọ̀ àti òyè ni.
Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì àgbà fún ààrẹ Buhari lóri ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́, Garba Shehu ló fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan tó fọ́wọ́ si láti kí Olusegun Obasanju fun ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin.
Àtẹjáde náà ni " Ààrẹ Muhammadu Buhari bá ààrẹ àná Olusegun Obasanjọ yọ fun ayẹyẹ ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin"
- Ọpẹ́lọpẹ́ àjẹsára, ó yẹ kí n ti kú lẹ́yìn tí àwọn jàǹdúkú ṣá mi ní àdá - Oyinkansola Elebuibon
- Wọn yóò yẹgi fún àwọn ọmọ Nàìjíríà méjì lórí ikú ọmọbìnrin Takoradi tó dàwátì ní Ghana
- Wọ́n ti tú akọ̀ròyìn BBC, Girmay Gebru sílẹ̀ kúrò látìmọ́lé ní Tigray
- Baba tó dàbí MC Oluomo láyé yìí kò sí, ẹni tó bá níi, ó ní ohun gbogbo- Ọmọ MC Oluọmọ
- Ẹ fi Sunday Ìgbòho sílẹ, ǹkan tí ìjọba Nàìjíríà bàjẹ́ ló ń gbìyànjú àti túnṣé; Ìjọba àpapọ̀ ní láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀ - Wole Soyinka
" Lórúkọ ìjọba Nàìjíríà , ààrẹ Muhammadu Buhari gbàdúra pé ààrẹ to ti sin orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pẹ̀lú ìfẹ́, ìfọkànsìn, àti ìfarajì tẹ̀síwájú láti má wa lori èèpẹ̀ ilẹ̀ ní àláfíà àti ìdùnú
"Ààrẹ Buhari ni orílẹ̀-èdè yìí yóò túnbọ̀ máa gbójú sókè fún ìmọ̀ àti ìfọ̀kànsìn.
Bákan náà ni ààrẹ gbàdúrà kí Èèdùà lọ́ra ẹmi rẹ kí o lè pé fún orílẹ̀ èdè yìí.









