Benue news: Èèyàn méjì kú lásìkò tí ṣọ́ọ̀ṣì dà wó ní Taraba, àwọn míràn farapa

Oríṣun àwòrán, Facebook: Treasuregist
Ile ijọsin kan ti wo pa eeyan meji ni ipinlẹ Taraba, nigba ti awọn olujọsin mii farapa.
Ile ijọsin Holy Ghost Church to wa ni ijọba ibilẹ Takum ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Alaga ijọba ibilẹ ọhun, Shiban Tikari lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin.
- Ẹ dákun ẹ ran Iyabo Oko lọ́wọ́, ìyá ti ń ṣàárẹ̀ láti ọdún márùn ún sẹ́yìn, o ti kọjá agbára wa- Foluke Daramola Salako
- Wo iye kọ́ńdọ́mù táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ń ṣara rindin lọ́dún
- Wo ìdí tí àwọn obìnrin kan fi n yọ ilé ọmọ wọn kúrò
- Wo díẹ̀ lára bí wọ́n ṣe sàmì ìrántì ìkọlù 9/11 ní America
- Kí ló lè mú ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tó wà ní ND2 yìí pokùnso?
- Ọmọ Naijiria tó ń ṣe Yahoo rí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ̀rin he l'Amẹrika
- Aàrẹ Joe Biden pè fún alàáfíà àti ìrẹ́pọ̀ lẹ́yìn ogún ọdún tí ìkọlù 9/11 wáyé ní America
Iroyin ni isin n lọ lọwọ ni ile ijọsin naa wo, to si gbẹmi eeyan meji ọhun, Demenege James adti Mwueze Terzunwe.
Alaga ijọba ibilẹ naa fi kun pe awọn eeyan to farapa ti wa nile iwosan nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Ẹwẹ, awọn janduku tun ti ṣoṣẹ ni abule kan to wa ni ala ipinlẹ Taraba ati Benue, nibi ti wọn ti pa eeyan kan, ti wọn si ji awọn mii gbe lọ.
Iroyin sọ pe ọpọ awọn olugbe abule naa to wa ni Benue lo salọ si agbegbe Koffai Ahmadu to wa ni ijọba ibilẹ Takum, ni Taraba lọjọ Abamẹta.
Alaga ijọba ibilẹ naa ṣalaye fun awọn akọroyin pe oun ti ke si awọn eleto abo lati ji giri si iṣẹ wọn lagbegbe ọhun ki ọrọ naa ma baa kọja bo ṣe yẹ lọ.
Alaga ọhun pari ọrọ rẹ pe ọwọ awọn agbofinro ko tii tẹ ọkankan lara awọn janduku naa titi di akoko ti a n ko iroyi yii jọ.
- Àwa ọmọ ìlú Igboho kò gbàbọ̀dè fún Sheikh Gumi o, gbọin-gbọin ni à wà lẹ́yìn Sunday Igboho
- Ògiri amọ̀ wó pa ènìyàn méjì n'Ibadan
- Àwọn ajínigbé ti tú àwọn òṣìṣẹ́ ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo sílẹ
- Wo ìdí tí ìwọ́de Yorùbá Nation kò fi ní wáyé mọ́ lónìí nílùú Sunday Igboho
- Nǹkan yan! Ìrẹsì, Spaghetti àti sìgá làwọn agbébọn ń béèrè fún ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n bá jí gbé báyìí













