Depression: Akẹ́kọ̀ọ́ Auchi Poly tó wà ni ND2 pokùnso ní ìpínlẹ̀ Edo

Suicide

Oríṣun àwòrán, Tammy Cuff

Ẹni ọdun mẹtalelogun kan, to jẹ akẹkọọ ile ẹkọ gbogboniṣe to wa niluu Auchi, nipinlẹ Edo, ti jade laye lẹyin to gbẹmi ara rẹ.

Iroyin sọ pe awọn alabagbe akẹkọọ naa ṣawari oku rẹ nibi to so rọ si loke aja ninu yara rẹ lalẹ ọjọ Ẹti.

Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, oloogbe ọhun kọ lẹta ko to so ara rẹ rọ.

Ẹnikan ti ko fẹ ki awọn akọroyin fi orukọ rẹ lede sọ pe oloogbe ọhun ni ki wọn fun ọdọbinrin kan, Sandra ni ẹrọ ilewọ oun, ati pe ki ọdọbinrin naa forijin oun ninu lẹta to kọ ko to gbẹmi ara rẹ.

Ẹni naa ṣalaya pe Sandra yii ni ọrẹbinri oloogbe ọhun, kilaasi kan ni awọn mejeji si wa.

O ni "Solomon ṣi wa si kilaasi lọjọ Ẹti, ṣugbọn nigba ti a dele ni a ba oku rẹ nibi to so rọ si loke aja yara rẹ."

Àkọlé fídíò, Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....

"O jẹ ẹnikan ti ko le sọ ti ẹnu rẹ tan o si mu ẹkọ rẹ ni okunkundun."

"Kii jade lọpọ igba ṣugbọn ko fi apẹrẹ han bii ẹni o wa ninu ibanujẹ kankan tabi irẹwẹsi ọkan."

Àkọlé fídíò, ''N15m làwọn Fulani ajínigbé kọ́kọ́ bèèrè kí wọ́n tó gba N2.5m ọ́wọ́ wa l'Abuja''

Agbẹnusọ ile ẹkọ naa, Mustapha Oshiobugie ṣo pe lootọ ni iṣẹlẹ ọhun waye, amọ wọn ko tii ṣalaye fun oun bo ṣe ṣẹlẹ lẹkunrẹrẹ.

Ipele kinni, ND1, ni akẹkọọ naa wa ni ẹka imọ Public Administration ko to fi aye silẹ.