Ibadan flood: Omi gbé arákùnrin ẹni ọdún 28 kan lọ ní Ibadan, Gómìnà Makinde bá mọ̀lẹ́bí kẹ́dùn

awọn eeyan nibi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, Insideoyo.com

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ti kan sí mọlẹbi arakunrin kan to padanu ẹmi rẹ ninu ìṣẹlẹ omiya'le agbara ya sọọbu kan ni Ibadan.

Adugbo Onilu Moniya ni arakunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn naa Abiodun Adeleke ti ba omi lọ.

Gẹgẹ bí iroyin to tẹwa lọwọ ninu ọjọ to ya ile ya sọọbu ní o ti padanu ẹmi rẹ lasiko to n ran awọn ọlọkada lọwọ lati sọdá odo Asanmajana.

A gbọ pé omi gbè lọ nibi to ti n ran awọn eeyan lọwọ ni.

Gomina Makinde lasiko àbẹwò si awọn ẹgbẹ onile ladugbo Onilu ba mọlẹbi ati araadugbo kẹdun iṣẹlẹ buruku yi

Ọgá agba ileesẹ to n mojuto àtúnṣe ojú ọnà Kamil Akinlabi to soju Gomina fi idaniloju hàn s'àwon araadugbo pe ìjọba yoo wa nkan ṣe sí iru iṣẹlẹ yi.

" Iṣẹlẹ iku ọmọ yín yi fọwọ kan wa l'ẹmi.A gba ladura ki eledua rẹ mọlẹbi rẹ l'ẹkun lori ikú rẹ"

Àkọlé fídíò, ''N15m làwọn Fulani ajínigbé kọ́kọ́ bèèrè kí wọ́n tó gba N2.5m ọ́wọ́ wa l'Abuja''

Alaga ẹgbẹ awọn oníle ladugbo náà arakunrin Bukola Akintola dupẹ lọwọ Gomina nipa kika oroy iṣẹlẹ naa kun.

O ni púpọ awọn alaṣẹ lo ti n wa lori ọrọ omiyale yi ti kò sí seso kankan.

O wa rọ Gomina Makinde lati mu adehun rẹ ṣe sí awon araadugbo laipẹ.