Gómìnà Zamfara ní kò sí ìdáríjí fún àwọn jàndùkú mọ́ ní ìpínlẹ̀ òun

Oríṣun àwòrán, others
Gomina ipinlẹ Zamfara, Bello Matawalle ti sọ pe ijọba oun ko ni maa ṣe aforiji fun awọn janduku mọ nitori wọn ti gun igi kọja ewe.
O ni awọn gbe igbesẹ yii lẹyin ti gbogbo igbiyanju ijọba lati ni ijiroro alaafia pẹlu awọn janduklu naa ja si pabo.
Matawalle lo sọ ọrọ naa nibi eto adura kan to waye ni Mọṣalaṣi Gusau, ni ipinlẹ ọhun.
- Ìwádìí ti tú àṣírí àwọn tó yìnbọn sí olùwọ́de EndSARS ní Tollgate l'Eko
- Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Odunlade Adekola nídìí iṣẹ́ tíàtà sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn pé ó ń bá àwọn lòpọ̀
- Arákùnrin ẹni ọdún 28 kan tí bá omiyalé lọ ní Ibadan
- Ọ̀bẹ ti bá ọ̀gá DPO tó sọ ìbọn ọlọ́pàá nu lẹ́yìn tó gbé obìnrin sùn sí ọ́fíìsì rẹ̀ nídí
- Àwa ọmọ ìlú Igboho kò gbàbọ̀dè fún Sheikh Gumi o, gbọin-gbọin ni à wà lẹ́yìn Sunday Igboho
- Ògiri amọ̀ wó pa ènìyàn méjì n'Ibadan
O ni "Awọn janduku naa ran awọn eeyan kan lati bẹ wa pe ki a ṣi ọna fun wọn lati maa ko ounjẹ lọ sibi ti wọn wa, ṣugbọn mo kọ jalẹ."
"Ohun ti a oo maa ṣe bayii ni pe a oo maa ran wọn lọ si ọrun lati lọ jẹjọ lọdọ Eledumare."
Gẹgẹ bii ohun ti gomina naa sọ, awọn janduku naa ti n foju wina ija awọn agbofinro, opin yoo si de ba wọn laipẹ.
O ni lootọ ni awọn ọdaran naa ti kọkọ ṣetan lati joko fun ijiroro lori eto abo to mẹhẹ ni Zamfara, ṣugbọn bayii o ti bọ sori.
Lẹyin naa lo gba awọn olugbe ipinlẹ ọhun nimọran lati ṣe suuru nitori ọrọ awọn janduku yoo di ohun igbagbe laipẹ jọjọ.
O tun rọ awọn oloṣẹlu lati dẹkun ati maa ra alupupu fun awọn eeyan gẹgẹ bii ohun amuṣagbara.
Gomina naa pari ọrọ rẹ pe pupọ ninu awọn ti awọn oloṣelu n ra alupupu fun lo maa n ta awọn alupupu naa fun awọn janduku, eyii ti awọn janduku ọhun fi ṣiṣẹ ibi.
- Nǹkan yan! Ìrẹsì, Spaghetti àti sìgá làwọn agbébọn ń béèrè fún ìtúsílẹ̀ àwọn tí wọ́n bá jí gbé báyìí
- Àlàyé ohun tọ́rọ̀ adarí ń dá sílẹ̀ ní ìjọ Synagogue lẹ́yìn ikú TB Joshua rèé
- Ọkùnrin ẹlẹ́wọ̀n kan wọ gàù lẹ́yìn tó gé kórópọ̀n ẹlẹ́wọn míràn
- Ìjọba Ondo bẹ́gilé ẹgbẹ́ ọlọ́jà, ó ní wọ́n ń ni aráàlú lára
- Wo ìgbésẹ tí Sunday Igboho fẹ́ gbé báyìí lórí àwọn agbẹjọ́rò Cotonou tó ní wón ń gba N4m sí N3m lọ́wọ́ òun














