Boko Haram: Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà tí UAE ń wá lórí ẹ̀sùn ṣíṣe àtìlẹ́yìn owó fún Boko Haram

Oríṣun àwòrán, AFP
Ijọba orilẹede UAE ti kede pe oun n wa ọmọ Naijiria mẹfa to n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram.
Awọn mẹfa yii lo wa lara eeyan mejinlogoji ti UAE kede pe awọn n wa lori ẹsun pe wọn n ṣagbatẹru fun igbesunmọmi.
Abdurrahaman Ado Musa, Salihu Yusuf Adamu, Bashir Ali Yusuf, Muhammed Ibrahim Isa, Ibrahim Ali Alhassan ati Surajo Abubakar Muhammad ni awọn ọmọ Naijiria mẹfa ọhun.
- 'Màmá mi, Iyabo Oko ti ní "Left Stroke" ní fọ́tò wọ́n ṣe rí bẹ́yẹn o àmọ́...'
- Kókó nǹkan tí ẹgbẹ́ NINAS ń bèrè fún ní ibi ìpàdé UN General Assembly
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
- Ilẹ̀ ń j'ẹ̀nìyàn, ìyá ìyàwó gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀ Florence Ajimobi jáde láyé
- Wo ohun táwọn ọmọ Nàìjíríà ti pàdánù lẹ́yìn tó pé ọgọ́rùn ún ọjọ́ tí ìjọba ti f'òfin de Twitter
- Ọ̀gá ọlọ́pàá Èkó kàn sí ẹbí Monsurat tí ọlọ́pàá yìnbon lù
- Lébìrà tó jí iriniṣẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná a fi ẹgba àtòrì méjìlá ṣara rindin kó lè kọ́ ẹ̀kọ́
- 'Ó lé ni akẹ́kọ̀ọ́ 1,000 tí àwọn ajínigbé kó láàrin oṣù kíni sí ìkẹjọ 2021'
- Ta ni Ola Ibironke, ọkọ Bimbo Oshin to dólògbé?
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
Iroyin sọ pe ni nkan bi ọdun kan sẹyin ni orilẹede UAE kede pe awọn ọmọ Naijiria naa n ṣe atilẹyin fun Boko Haram.
Awọn ọmọ orilẹede mii ti ilẹ UAE n wa ni Ahmed Mohammed Abdulla Mohammed Alshaiba Alnuaimi (UAE), Mohamed Saqer Yousif Saqer Al Zaabi (UAE), Hamad Mohammed Rahmah Humaid Alshamsi (UAE), Saeed Naser Saeed Naser Alteneiji (UAE) pẹlu Hassan Hussain Tabaja (Lebanon).
Awọn miran tun ni Adham Hussain Tabaja (Lebanon), Mohammed Ahmed Musaed Saeed (Yemen), Hayder Habeeb Ali (Iraq), Basim Yousuf Hussein Alshaghanbi (Iraq) ati Sharif Ahmed Sharif Ba Alawi (Yemen).
Ileeṣẹ iroyin kan lati UAE ṣalaye pe ijọba gbe orukọ awọn eeyan yii jade gẹgẹ bi ọkan lara ọna lati bi dẹkun awọn eeyan to n ṣagbatẹru igbesunmọmi.
Ẹwẹ, ile ẹjọ giga Abu Dhabi dajọ ẹwọn gbere fun ọmọ Naijiria meji, Surajo Abubakar Muhammad ati Saliuh Yusuf Adamu.
Bakan naa tun ni ile ẹjọ ni ki wọn fi orilẹede naa silẹ.
Ile ẹjọ dajọ ẹwọn ọdun mẹwaa fun Ibrahim Ali Alhassan, AbdurRahman Ado Musa, Bashir Ali Yusuf ati Muhammad Ibrahim Isa, to si tun sọ pe ki wọn fi orilẹede UAE silẹ.
Ile ẹjọ tun ni wọn jẹbi ẹsun dida ọgba ẹwọn Boko Haram silẹ.
Awọn eeyan yii ni wọn ni wọn fi owo to to $800,000 ṣe atilẹyin fun Boko Haram laarin ọdun 2015 si 2016.












