Police shooting: Ọlọ́pàá Eko ní àwọn ti mú aríbọnyọ̀ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa arábìnrin kan ní Ijeshatedo ní Sátidé

Oríṣun àwòrán, other
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ni awọn ti fi panpaẹ ofin gbe aribọnyọ ọlọpaa to yinbọn gbẹmi arabinrin ẹni ọdun mejidinlogun kan lagbegbe ijẹṣatedo ni ipinlẹ Eko lọj Abamẹta.
Wahala waye lagbegbe naa lọsan ọjọ Abamẹta nigba ti awọn ibọn ọlọpaa kan lati ikọ ọtẹlẹmuyẹ SCID Panti ba arabinrin Monsurat Ojuade.
- Ọ̀bẹ ti bá ọ̀gá DPO tó sọ ìbọn ọlọ́pàá nu lẹ́yìn tó gbé obìnrin sùn sí ọ́fíìsì rẹ̀ nídí
- Ìyàwó Wòlíì TB Joshua di olórí ìjọ Synagogue
- Ẹ dákun ẹ ran Iyabo Oko lọ́wọ́, ìyá ti ń ṣàárẹ̀ láti ọdún márùn ún sẹ́yìn, o ti kọjá agbára wa- Foluke Daramola Salako
- Ṣọ́ọ̀ṣì wó pa èèyàn méjì ní Taraba, àwọn míràn farapa
- Wo iye kọ́ńdọ́mù táwọn ọmọ Nàìjíríà fi ń ṣara rindin lọ́dún
Atẹjade kan lati ọdọ Adekunle Ajiṣebutu to jẹ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ni aṣita ibọn ni iṣẹlẹ naa ati pe awọn ọlọpaa naa lọ si agbegbe naa lati lọ mu afurasi adigunjale kan ni ati pe wọn gbiyanju ati doola ẹmi rẹ ṣugbọn o ti ku ki wọn to de ileewosan.
O fi kun un pe kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Hakeem Odumoṣu ti paṣẹ pe ki wọn gbe ọlọpaa naa lọ sileẹjọ ni kete ti wọn ba ti gba iṣẹ lọwọ rẹ lati lee jẹ ifaleti fun awọn ọlọpaa ẹgbẹ rẹ.








