Awo Stage Play: Wo eré, ijó àti orin tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ayé Awolowo àti aya rẹ̀
Arise ni arika, arika si ni baba iregun, ohun ta ba se lonii, itan ni yoo da to ba di ọla, o yẹ ka gbe ile aye se rere.
Oloye Obafemi Awolowo jẹ odu, ti kii se aimọ fun awọn oloko ni agbo awọn ọmọwe ati oselu to ti kọja lọ lorilẹede Naijiria.
Awolowo yii si wa laarin awọn akọni ọmọ Naijiria to gbe ina wo oju awọn oyinbo amunisin lati gba ominiria fun Naijiria.
Bakan naa lo ti tukọ ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, to si se gudugudu meje ati ya ya ya mẹfa fun iran Yoruba lasiko rẹ.
Amọ o se ni laanu pe awọn ọdọ iwoyii ti ọjọ ori wọn ko ju ogun si ọgbọn ọdun lọ ko mọ nipa awọn ribiribi ti Awolowo gbe ile aye se tabi iru eeyan to jẹ.
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?
- Àwọn ohun èèlò tí Olóògbé Olóyè Obafemi Awọ́lọ́wọ̀ lò gbẹ́yìn
- Ìtan ìgbé ayé Olusegun Obasanjo kọ́ wa nípa sùúrù atápáta-dìde
- 'Láì ní ìwé mẹ́wàá, orí sún mi bá're di dẹ́rẹ́bà Awolowo, Azikwe, Gowon'
- Dẹ́rẹ́bà Awolowo Pa Olabode Olajide ti jáde láyé
Ọna lati mase jẹ ki isẹ awọn akọni Naijiria bii Awolowo parun lo mu ki wọn se agbekalẹ ere onise yii ti yoo kọ awọn ọdọ iwoyi ni ẹkọ nipa igbe aye Awolowo ati aya rẹ, Hannah Dideolu Awolowo, HID.
BBC Yoruba ba wọn peju si ibudo ti ere onise ati orin pẹlu ijo naa ti waye, eyi ti igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ati aya rẹ Dolapo, tii se ọmọ-ọmọ Awolowo peju si.
Awọn alejo pataki miran to tun wa nibẹ ni gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu àti ọmọ-ọmọ Awolowo miran, Olusegun, adari ile asoju-soju, Femi Gbajabiamila to fi mọ awọn eekanlu miran.
- Àwọn èèkàn ìlú péjú s'Ibadan níbi ìsìnkú màmá Omotola àkọ́bí obìnrin Awolowo tó wọ káà ilẹ̀ lọ
- Ọ̀rọ̀ aàbò ní Nàìjíríà ti di kí olórí dorí ẹ mú- Femi Falana
- "Ìgbéyàwó wa pé ọdun mẹ́ẹ̀dógún, àmọ́ ìgbà mẹ́wàá péré la ní ìbálòpọ̀"
- Ọ̀gá ọlọ́pàá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí wọ́n lọ fi ṣìkún òfin mú àwọn ọlọ́kadà nílùú Eko
- Ajá gé ǹkan ọmọkùnrin akẹkọọ AAUA ní Akungba jẹ ní àwọn agbófinró bá mú ajá náà
Eto miran ti won tun gbekale lati fi sami iranti aya Awolowo naa ni ti ifilole iwe nipa Awolowo ti ogbontarigi onkowe kan ko fun iranti akoni naa.
Ogbeni Lagada Abayomi to je gbajugbaja onkowe ati sorosoro to ko iwe naa ba BBC Yoruba soro lori pataki ki awon omo iwoyi mo sii nipa ipa ti akoni eda naa ko ninu itan iselu Naijiria.
Bee bi omo ko ba ba itan, o di dandan ko ba aroba to je baba itan.
- Ìtan ìgbé ayé Olusegun Obasanjo kọ́ wa nípa sùúrù atápáta-dìde
- Agbẹjọ́rò Sunday Igboho fèsì padà fún Malami lórí ẹ̀sùn tuntun tó fẹ́ fi kan oníbàárà rẹ̀
- Àwọn èèkàn ìlú péjú s'Ibadan níbi ìsìnkú màmá Omotola àkọ́bí obìnrin Awolowo tó wọ káà ilẹ̀ lọ
- Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?




