Okada ban in Lagos: Ẹ̀mí ọ̀gá ọlọ́pàá sọnù lásìkò tí wọ́n lọ fi ṣìkún òfin mú àwọn ọlọ́kadà nílùú Eko

Oríṣun àwòrán, Kazeem Abonde
Ọga ọlọpaa kan, CSP Kazeem Sumonu Abonde, ti padanu ẹmi rẹ niluu Eko lasiko ti ija bẹ silẹ laarin awọn oṣiṣẹ igbimọ amuṣẹya to n gbẹsẹle ọkada.
Iṣẹlẹ naa waye lagbegbe Ajao Estate lasiko ti awọn agbofinro lati ẹka RRS, igbimọ amuṣẹya to n gbẹsẹle ọkada atawọn ọlọpaa lati egbege naa lọ ṣawari awọn afurasi kan.
Ninu atẹjade ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni ẹmi ọga ọlọpaa ọhun sọnu lasiko ti wọn lọ fofin de awọn ọlọkada lagbegbe ọhun.
- "Ìgbéyàwó wa pé ọdun mẹ́ẹ̀dógún, àmọ́ ìgbà mẹ́wàá péré la ní ìbálòpọ̀"
- Agbẹjọ́rò Sunday Igboho fèsì padà fún Malami lórí ẹ̀sùn tuntun tó fẹ́ fi kan oníbàárà rẹ̀
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sí aṣọ lójú afurasí agbófinró tó pa Monsurat Ojuade, ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ lóní
- Mo ta ọkọ̀ ayọkẹ́lẹ́ méjì lórí àìsàn yìí, mo nílò ìrànwọ́ ẹ̀yin olólùfẹ́ mi - Iyabo Oko
- FFK ti kó èébì rẹ̀ jẹ, Buhari dáa pẹ̀lú bó ṣe gba ọmọ onínàákúnàá padà - Femi Adesina
- Buhari san $500 fáwọn aláwọ̀ dúdú l‘Amẹ́ríkà láti takò ẹ̀hónú wa - Yoruba/Biafra Nation
- Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ ló fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ mí, àyàfi Dudu Heritage nìkan
- 'Ó kéré tán, Nọ́ọ̀sí alábẹ́rẹ́ 7,000 ló ń sá kúrò ní Nàìjíríà ní ọdọọ́dún'
Ajisebutu sọ pe "Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn oṣiṣẹ wa yoo lọ mu awọn ọlọkada to kọti ikun si aṣẹ ijọba ipinlẹ Eko lori ọkada wiwa lawọn agbegbe kan."
"Awọn agbofinro n ṣiṣẹ naa lati mu adinku ba iwa ọdaran niluu Eko, a si ti fi sikun ofin mu ọpọlọpọ sawọn ọdaran nipasẹ irufẹ iṣẹ bẹẹ."
"Ṣugbọn ọ ṣeni laanu pe lẹyin ti a fi ṣikun ofin mu awọn ọdaran kan tan ni Ajao Estate ni awọn ẹmẹwa wọn dena de awọn oṣiṣeẹ wa pẹlu ada, ibọn ati oniruru ohun ija oloro ti wọn si kọlu awọn eeyan naa nibi ti CSP Kazeem Sumonu Abonde ti jade laye."
Ajisenutu tẹsiwaju pe yatọ si ọga ọlọpaa to ku yii, DPO agọ ọlọpaa to wa ni Ajao Estate, CSP Abdullahi Malla atawọn ọlọpaa mii tun farapa loriṣiriṣi.
O fi kun pe awọn ti gbe oku ọga ọlọpaa to dagbere faye naa lọ sile igbokupamọsi.
Ẹwẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ọhun, o si ti paṣẹ ki iwadii kikun bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.
Lẹyin naa lo ṣeleri pe irufẹ ikọlu bẹẹ ko ni waye mọ labẹ idari oun, ati pe iṣẹlẹ naa ko ni da omi tutu sọkan awọn agbofinro ipinlẹ Eko.














