Nursing and Midwifery Council of Nigeria: Nàìjiíríà pẹ́lù ibi ti àwọn nọ́ọ̀sí wọn ti kúnjú òṣùwọ̀n jùlọ ní àgbáyé

Oríṣun àwòrán, others
Akọwe agba ajọ Nursing and Midwifery Council of Nigeria, Dr Faruk Abubakar ti ni o kere tan ẹgbẹrun meje awọn nọọsi ni wọn n kuro lorilẹede Naijiria lọ si ibomiran ni ọdọọdun.
Abubakar ni eyi fihan gbangba pe awọn nọọsi lorilẹede Naijiria pẹlu awọn to lamilaaka, ti wọn si mọ iṣẹ wọn ni iṣẹ kaakiri agbaye.
Ni ipinlẹ Delta ni Abubakar ti sọ ọrọ yii lasiko to n gba awọn nọọsi ti wọn ṣẹṣẹ ṣe idanwo abajade tan ni iyanju nipinlẹ naa.
- Ìyanṣẹ́lódì míràn kò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ àyàfi tí Ijọba àpapọ̀ bá....- ASUU
- Òní nilé ẹjọ́ yóò dájọ́ lórí awuyewuye owó oṣù àwọn dókítà pẹ̀lú ìjọba
- ECOWAS f'òfin de àwọn ológun tó dìtẹ̀ gbàjọba ní Guinea
- Iléẹjọ́ ti ní kí ìjọba Nàìjíríà san ogún bílíọ̀nù fún Sunday Igboho gẹ́gẹ́ bí owó gbà má bínú!
- Agbẹnusọ àjọ EFCC Wilson Uwujaren ti ṣàlàyé nǹkan tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀gá àjọ náà lósàn ọjọ́bọ
Abubakar ni o pọn dandan ki awọn nọọsi tẹ ipa mọ iṣẹ wọn, ki idagbasoke tunbọ ma a ba wọn lẹnu iṣẹ lai ni ifasẹyin.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn onimọ ni ẹka eto ilera kaakiri Naijiria ṣe n fi orilẹede naa silẹ lọ si ibomiran nitori aiṣedede ijọba apapọ si wọn, ti wọn ko san owo oṣu wọn deede ati aipese awọn ohun elo ti wọn nilo lati ṣe iṣẹ wọn bi iṣẹ.
Amọ, kọmiṣọnna fun eto ilera nipinlẹ Delta, Dokita Ononye bu ẹnu atẹ lu bi awọn nọọsi ṣe n kuro ni Naijiria ni ọgọọrọ lọ si awọn orilẹede miran
Ononye ni ti ijọba ko ba bojuto ọrọ yii ni kiakia, nkan yoo tunbọ bajẹ si ni ẹka eto ilera ni Naijiria.
''O ṣeeni laanu wi pe awọn nọọsi ati dokita ti wọn gba ẹkọ ni Naijiria ni owo perete wa n kuro lorilẹede naa lọ si ibomiran lati lo lo imọ wọn fun awọn ibi ti wọn lọ tẹdo si.''
''Eleyii jẹ ibanujẹ ọkan fun awọn adari ni ẹka eto ilera lorilẹede Naijiria nitori eto ilera ti mẹhẹ sibẹ tẹlẹ.''
Kọmisọnna fun eto ilera nipinlẹ Delta wa rọ awọn nọọsi naa lati tẹpa mọ iṣẹ wọn, ki ijọba naa si gbiyanju lati mu igbega ba eto ilera ni Naijiria.
- A ti gbálé ati gbáta, kò sí ǹkankan lọ́wọ́ wa mọ́ ni a ṣe kígbe síta- Adebisi Aisha, Ọmọ Iyabo Oko
- Kí ẹnikẹ́ni má gbé ìyá mi síta mọ́, mí o ní agbẹnusọ kankan mọ́- Sunday Igboho
- ''Ìjọba, ẹ má da àwa tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation pọ̀ mọ́ IPOB''
- ''APC yóò fún Goodluck Jonathan ní ànfàní láti dupò ààrẹ lọ́dún 2023 tó bá darapọ̀ mọ́ wa''
- Ọkùnrin tó lẹ ''Super Glue'' mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ''condom'' ti dèrò ọ̀run
- Wo iye ìgbà tí bàálù ìjagun ti já tó sì ṣekú pa àwọn ènìyàn ní Nàìjíríà


















