Soldier beats Corp Member: Àgùnbánirọ̀ Fidelia ti sọ́jà tó da omi ìdọ̀tí lé e lórí ní ìṣẹ̀lẹ̀ ń mú ojú ti òun

Oríṣun àwòrán, Ifeyinwa Fidelia
Yoruba bọ, wọn ni ẹni to ba ta ọfa soke, to yi odo bori, bi ọba aye ko ri i, ti ti ọrun n wo o.
Aje iwa ibajẹ ti ọmọogun obinrin kan, Chika Viola Anele, hu si agunbanirọ obinrin kan ni ilu Calabar, Ezeiruaku Ifenyinwa Fidelia, ti ṣi mọ ọ lori bayii lẹyin ti ileeṣẹ ọmogun ni awọn yoo fi iya totọ jẹ ẹ
Anele ni fidio kan to gbori ayelujara pa ṣafihan bi o ṣe n da omi idọti sori Fidelia titi ti gbogbo aṣọ rẹ fi tutu tan.
- 'Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, "ọ̀ín" kí ló burú níbẹ̀?'
- Àlàyé rèé lórí bí sọ́jà ṣe lu àgùnbánirọ̀ obìnrin, tó da omi ìdọ̀tí le lórí
- Òntàjà góòlù wọ́ Bobrisky nìlẹ̀ pé ó ra góòlù àwìn tó wọ̀ lọ́jọ́ ìbí rẹ̀ láì san owó pé
- "Ìgbéyàwó wa pé ọdun mẹ́ẹ̀dógún, àmọ́ ìgbà mẹ́wàá péré la ní ìbálòpọ̀"
- Bí o bá ń fẹnukonu ju iye ìṣẹ́jú ààyá yìí lọ, wo adúrú kòkòrò tí wàá tí ibi ẹnu kò
Ẹwẹ, Fidelia ti sọrọ lori iṣẹlẹ naa fun igba akọkọ lati igba ti sọja naa ti fi iya jẹ ẹ.
Nigba ti o ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to pada si ilu Eko, Fidelia ni niṣe loju maa n ti oun nigba kugba ti oun ba ti ranti iṣẹlẹ naa.
Fidelia ni ''ọpọ eeyan lo ti n pe mi lori ago kaakiri orilẹede Naijiria ti wọn n sọ fun mi awọn ri fọto iṣẹlẹ naa.
Iṣẹlẹ ọhun ti jẹ ki n di ilumọọka bayii pẹlu bi fidio iṣẹlẹ naa ti lu ori ayelujara pa.''
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ iru ṣeria to fẹ ki wọn da fun ọmogun naa, o ni iru idajọ to yẹ ni wọn da fun un.
Fidelia sọ pe ko si iru ijiya ti wọn fun ọmogun naa ti ko tẹ oun lọrun.
O tun fikun ọrọ rẹ pe awọn ọmogun ko dunkoko mọ oun pe oun ko gbọdọ sọ nipa iṣẹlẹ naa fawọn akọroyin.
Bakan naa ni o fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn akẹgbẹ ọmogun naa lo bu ẹnu atẹ lu iwa ti Anele hu.
Ileeṣẹ ologun ti kede pe esi idajọ Anele yoo jade faye gbọ laipẹ lori iwa to hu si Fidelia niluu Calabar.
















