Bobrisky: Òntàjà góòlù wọ́ Bobrisky nìlẹ̀ pé ó ra góòlù àwìn tó wọ̀ lọ́jọ́ ìbí rẹ̀ láì san owó pé

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Bobrisky

Ọrọ iwe mimọ lo sọ pe iwọ ti o fẹ yọ igi loju ẹlọmiran, o kọkọ gbọdọ yọ iti igi to wa loju tiẹ na.

Bẹẹ gẹgẹ lo ri fun ilumọọka ọkunrin to n wọ aṣọ obinrin, Bobrisky, nigba ti ontaja goolu kan wa wọ nilẹ loju opo Instagram, lori ẹsun pe o gba awin goolu to wọ lọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

Ohun to mu ọrọ yii wa ni bi Bobrisky ṣe tabuku gbajumọ osere tiata kan, Tonto Dikeh, tii se ọrẹ timọtimọ rẹ tẹlẹ, loju opo Instagram pe o jẹ oun ni gbese miliọnu marun naira.

Ontaja naa ni bi Bobrisky ṣe tabuku Dikeh lo bi oun ninu lati tu aṣiri tiẹ naa lori ayelujara.

Ontaja goolu naa ni alagabagebe ati oniyẹyẹ eeyan lasan ni Bobrisky.

Ọhun ti ontaja goolu sọ nipa Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Houseofamearypearl

Koda o ni ika eeyan ni Bobrisky pẹlu nitori o ra goolu lọwọ oun lai bikita lati sanwo rẹ fun ọjọ pipẹ.

Ọlọja goolu naa ni ọrọ ko dun lẹnu Bobrisky lati maa fi Tonto Dikeh ṣe yẹyẹ pe o jẹ gbese nigba ti o jẹ pe oun gan an fun ra rẹ, onigbese ni.

Amọ, ontaja naa tọrọ aforijin lọwọ agbẹjọro rẹ pe oun fi ọrọ naa lede lori ayelujara lẹyin ti ọrọ naa ti de ile ẹjọ.

''O gba awin goolu lọwọ mi, o kọ lati fun mi lowo lẹyin oṣu meloo bayii.

O tun laya lati wọ goolu mi nibi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ, o fi ya fọto, o wa tun laya lati maa fi ẹnikan ṣe yẹyẹ.

Bobrisky, oniyẹyẹ ale Amuda ni ọ, alagabagebe si ni ọ pẹlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A ṣe iwọ naa le sọ pe ẹnikan n jẹ ọ lowo, abọwaaba ni ọrọ rẹ, onigbese jati jati.

Iwọ tiẹ gbagbe pe ẹni ti o ba n gbe ile gilaasi ko gbọdọ maa sọ oko ni.

Agbẹjọro mi, mo tọrọ aforijin tori ọrọ naa ti de ile ẹjọ bayii, mo si n reti idajọ lori ọrọ naa, o ti fẹ pe ọdun kan bayii.

Ohun ti onisowo goolu lori Instagram naa, houseofamearypearl kọ yoo, lo ti wa fọn kaakiri lori ayelujara.

Ọrọ Bobrisky kan dabi ikoko to n sọ pe idi kẹtu dudu ni jare,'' ontaja naa lo faraya bayii lori Instagram.

Saaju ni Bobrisky ti lo goolu ta n sọrọ rẹ yii, fi tadi rekereke niwaju olorin ni ọjọ ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

ohu

Oríṣun àwòrán, Houseofamearypearl