Kayode Fayemi: Aráàlú fọnmú lórí ìpè Fayemi láti sọ àgùnbánirọ̀tó bá fẹ́ di ológun

Awọn agunbanirọ

Oríṣun àwòrán, NYSC Information/Facebook

Ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu gomina ipinlẹ Ekiti, Kayode Fayemi lẹyin to rọ ijọba apapọ lati sọ eto agunbanirọ di eyii ti wọn yoo fi maa ṣe idanilẹkjọọ fun awọn to ba fẹ lati darapọ mọ ileeṣẹ ologun.

Ṣaaju ni Fayemi ti kọkọ sọ nibi idanilẹkọ kan ni fasiti ijọba apapọ to wa niluu Ibadan, UI, pe ọna to rọrun ju lati yanju iṣoro igbesumọmi ni lati ṣe atunṣe si ofin to gbe eto agunbanirọ kalẹ.

Gẹgẹ bii ohun ti Fayemi sọ, ti wọn ba n ṣe idanilẹkọọ ọmọ ogun fun awọn agunbanirọ, wọn yoo wulo lati koju awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram, janduku atawọn ẹgbẹ mii to n da omi alaafia Naijiria ru.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "Awọn ti ko ba fẹran lati darapọ ileeṣẹ ọmọ ogun yoo maa sinru ni agbegbe wọn, ṣugbọn ijọba ko maa fun ni owo osu."

"Lọna ati ṣe moriwu fun awọn to ba gba lati darapọ mọ ileeṣẹ ọmọ ogun, wọn yoo gba iwe ẹri to yatọ si ti awọn akẹgbẹ wọn ati ami ẹyẹ."

Àkọlé fídíò, Adejoke Ewaede: Ìfẹ́ àṣà Yorùbá ló mú kí ń pinnu láti máa wọ aṣọ àdìrẹ̀ nìkan

"Wọn yoo si tun ni anfaani lati tete darapọ mọ ileeṣẹ ọmọ ogun ni kikun lẹyin isinru ilu wọn ati lati tete ri iṣẹ ijọba gba."

Bakan naa ni Fayemi tun sọrọ lori oniruuru ipenija eto aabo to n koju Naijiria lati ọwọ ikọ afẹjẹwẹ Boko Haram, awọn agbebọn, awọn to n pe fun iyapa Naijiria ati awọn ajinigbe.

O ni asiko yii kọ lo yẹ ka maa ti ọwọ oselu bọ eto aabo to mẹhẹ, to si pe fun irẹpọ laarin awọn ọmọ Naijiria atawọn ọba alaye.

Gomina ipinlẹ Ekiti naa wa koro oju si bi iye eeyan to wa ni Naijiria n pọ si eyi ti ko ni odiwọn bayii, to si yẹ ka ronu ọna lati fun awọn ogo wẹẹrẹ wa ni eto ẹkọ to ye kooro.

Ṣugbọn nigba ti awọn eeyan n da si ọrọ naa lori ayelujara, wọn ni o yẹ ki Fayemi jẹ apẹrẹ rere, ko si ko awọn ọmọ rẹ wa lati oke okun wa darapọ mọ awọn ọmọ ogun naa.

Lara awọn eeyan naa lo fi erongba wọn lede lo koro oju si awọn erongba gomina ipinlẹ́ Ekiti naa, paapaa ipe fun amulo awọn agunbanirọ bii ologun.

Àkọlé fídíò, Ridwan Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́