Covid-19 Vaccine: Ìjọba ní òṣìṣẹ́ ọba tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára kò ní lè wọ ọọ́físì ṣiṣẹ́

Oríṣun àwòrán, WHO
Ijọba apapọ ti kede ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, ọdun yii fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
Alaga igbimọ ti Aarẹ gbe kalẹ lati bojuto ọrọ Covid-19 ni Naijiria, to tun jẹ akọwe ijọba apapọ, Bosss Mustapha lo kede gbedeke naa nibi ipade kan niluu Abuja.
O ni "Bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu kejila ọdun yii, ijọba apapọ yoo maa beere iwe ẹri gbigba abẹrẹ ajẹsara Covid-19, ati esi ayẹwo arun naa ki ẹnikẹni ninu awọn oṣiṣẹ ijọba to wọ ọọfisi wọn kaakiri Naijiria."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Odunlade, a fún ọ lọ́jọ́ méje, yọ sinimá tó ń fi ẹlẹ́hàá ṣe yẹ̀yẹ́ kúró lórí ayélujára - Ẹgbẹ́ THURIST
- Ẹ wo ọmọbabinrin ilẹ̀ Japan to sọ ipò iyebíye ti owó rẹ̀ tó $1.3m nù nítorí olólùfẹ́
- Ìgbésẹ̀ tà ń gbé rèé lórí ìlera Sunday Igboho àti ìtúsílẹ̀ rẹ̀ - Ilana Ọmọ Oodua
- Aṣòfin méjì wọ gàù lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ agbébọn
- Wo ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tó bá yọ kọ́ndọ́mù lásìkò ìbálòpọ̀ láì sọ
- "Bí ń kò sún mọ́ Sunday Igboho, ogun abẹ́lé kò bá ti wáyé ní Nàíjíríà"
- "Ẹ tètè gbé Sunday Igboho lọ fún ìtọ̀jú lókè òkun, kó tó pẹ́ jù"
- Buhari, dáríjin Igboho àti Kanu láti fòpin sí ìjìjàgbara ní Naijiria - Bíṣọ́ọ́bù ìjọ Elétò
- Òbí kan kó jàńdùkú lọ ká olùkọ́ tó na ọ̀mọ̀ rẹ̀ mọ́ iléẹ̀kọ́
"A oo fi atẹjade sita lori bi awọn ayẹwo naa yoo ṣe lọ."
Mustapha ṣalaye pe ijọba apapọ ti yọ South Africa, Brazil ati Turkey kuro lara awọn orilẹ-ede ti wọn ko gba ki awọn eeyan rẹ ṣabẹwo si Naijiria tẹlẹ.
O ni awọn gbe igbesẹ naa nibi ipade kan ti wọn ṣe ṣaaju ipade awọn akọroyin to ti kede igbeseẹ ijọba tuntun naa.
Lẹyin naa lo kan sara si ijọba ilẹ Gẹẹsi ni bo ṣe gba ki awọn ọmọ Naijiria to ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 maa ṣabẹwo silẹ ọhun.
Akọwe ijọba naa tun ran awọn ọmọ Naijiria leti nipa awọn ọdun awọn Musulumi ati ọdun Keresimesi to n bọ laipẹ, pe ọpọ ero ni yoo maa wọle-jade ni Naijiria, eyii ti yoo fa ki ọpọ eeyan korajọpọ soju kan.
O ni awọn yoo ṣeto lati bojuto bi awọn alejo ṣe n wọle ati bi wọn ṣe n jade ni Naijiria.
Lẹyin naa lo kilọ pẹ arun Covid-19 ṣi wa lode, nitori naa ki awọn eeyan maa fọ ọwọ wọn ni gbogbo igba, ki wọn ṣora fun ibi ti ọpọ ero pọ si, ki wọn si maa lo ibomu lawujọ.

















