ISWAP: Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria ní Abu Musab Al Barnawi ti jáde láyé

ISWAP

Oríṣun àwòrán, Daily Nigerian

Ọgagun kan nileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti sọ fun awọn akọroyin pe olori ọmọ ikọ Islamic State ni Iwọ Oorun ilẹ Afrika, ISWAP, ti jade laye.

Igba akọkọ ree ti ileeṣẹ ọmọ ogun yoo fidi ọrọ mulẹ pe lootọ ni Abu Musab Al Barnawi ti ku lati igba iroyin nipa iku rẹ ti gbode kan ninu oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Nigba to n fesi si awọn ibeere kan lasiko ipade awọn minisita niluu Abuja, ọga agba ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ni "Al Barnawi ti ku."

Bo tilẹ jẹ pe ko sọ bi olori agbesumọmi naa ṣe ku ati ibi ti o ku si, o kan fidi rẹ mulẹ pe o ti ku ni.

Ṣaaju ni awọn iroyin kan ti kọkọ n gbode pe olori ikọ ISWAP naa ti jade laye lẹyin to farapa nibi ija kan pẹlu awọn alatako ninu ẹgbẹ agbesumọmi kan naa ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2021 yii.

Ileeṣẹ iroyin BBC ko tii le fidi ọrọ naa mulẹ titi di akoko yii nitori ọpọ igba ni ileeṣẹ ọmọ yoo fi ọrọ sita pe awọn ti pa olori ẹgbẹ agbesumọmi ṣugbọn ti ọrọ ko ni ri bẹẹ.

Àkọlé fídíò, "Akokoro eyín lè ṣe ìpalára fún àtọ̀ ọkùnrin, ó sì lè yọrí sí ṣàkóbá fún ọkàn èèyàn"

Ẹwẹ, ẹgbẹ Islamic State naa ko tii sọ ni pato boya ni tootọ ni adari awọn ni iha Iwọ Oorun ti papoda ṣugbọn ninu oṣu Keje, wọn kede pe adari awọn, Abubakar Shekau jade laye lẹyin to gbẹmi ara rẹ pẹlu ẹwu ti wọn so ado oloro mọ lara.

Ọdun mẹwaa gbako ni Shekau fi dari ikọ Boko Haram.

Ṣugbọn ṣaaju iku Shekau ni ileeṣẹ ọmọ ogun ti maa n kede pe awọn ti pa a ṣugbọn lẹyin akoko diẹ si ikẹde wọn ni yoo sọrọ soke pe oun ṣi wa laye.

Wayi o, lẹyin iku Shekau ni ileeṣẹ ọmọ ogun kede pe ogunlọgọ awọn ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi jọwọ ara fun ijọba Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ridwan Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́