Dudu Heritage burial: Bí ọmọ mi obìnrin bá ń béèrè bàbá rẹ̀, ohun tí mo máa ń sọ fún un ni pé, bàbá rẹ̀ ti lọ bá àwọn áńgẹ́lì - Bimbo oshin

Mo ti sun ẹkun ti mi o sun laarin ọdun marindinlọgbọn mi gẹgẹ bi oṣere tiata, sibẹ, bi ala lo ṣi ri loju mi. Pẹlu omije loju ni mo n kọ ọrọ ikẹdun yii.
Eyi ni ọrọ ti gbajumọ oṣere, Bimbọ Ọshin fi bẹrẹ ọrs idagbere to ka nibi isinku ọkọ rẹ, oloogbe Ibironkẹ ti gbogbo eeyan mọ si Dudu Heritage.
"Mo ni anfani nla ti ko lẹlẹgbẹ lati jẹ iyawo fun ọkunrin to bẹru Ọlọrun to si tun nifẹ ati alaafia julọ ti obinrin kobinrin lee fi tọrọ. Ko si bi aye mi ṣe tun lee ladun laisi rẹ."
Ifẹ aye mi ni to ṣe ohun gbogbo to yẹ lati daabo bo mi lainaani oniruuru ikoju ati ariwisi. Oun ni eeyan kan ṣoṣo to mọ ohun ti a n pe ni ifẹ. Mo dupẹ pe mo lanfani lati baa rin irinajo ala rere to ni, ireti, ifẹ, ibanidọrẹ to yii ka."
- 'Olóyè Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ kánmọ́ kánmọ́ ráńṣẹ́ láti Cotonou nípà owó ìtọ́jú ìlera rẹ̀'
- Tùẹ̀, èsì yín ò jẹ wá! Ohun mẹ́rin tuntun táa ń bèrè lọ́wọ́ Òṣèré Odunlade àti TAMPAN rèé bí bẹ́ẹ̀ kọ́ - THURIST
- A pinu láti sinmi díẹ̀ lẹ́yìn ìgbeyàwó ká tó bímọ àmọ́ ó yíwọ́ - Wumi Toriola
- Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọ̀jọ̀gbọ́n Oyebode Adebowale, gíwá tuntun ní fásitì Ibadan
- Kò sí iṣẹ́ fún òṣìṣẹ́ ọba tí kò bá gba abẹ́rẹ́ àjẹsára títí December 1 - Ìjọba àpapọ̀
- Ìjọba fẹ́ máa tojú bọ ojú òpó WhatsApp yín, ₦4.87b ti wà nílẹ̀ láti mójú tóo - SERAP
Bimbọ Ọshin ni bi oun ba ti n ranti ọjọ kejila oṣu kẹsan ọdun 2021, inu oun kii dun.
O ni ọrọ to sọ kẹyin fun oun naa ni pe nigba ti oun fẹ lọ gbe ọmọ awọn ni ibudo iṣire Golf course ṣi n wa si iranti lọkan oun.

"Mo ṣi pe ẹ ni nnkan bii agogo meje ku iṣẹju diẹ lalẹ ọjọ naa nigba ti mo wa gbe ọmọ wa ni Golf Club gẹgẹ bi o ṣe sọ fun mi pe ki n ṣe. Ọkan mi ọ fun mi pe ki n pe ẹ lati yọju si mi ni ita nibi ti wọn n gbe ọkọ si. Mo pe ẹ o si ṣe nlẹ o iyawo ẹ, maa binu, mo wa ni ipade kan."
Ọrọ ajọsọ wọn to gbẹyin niyi.
O ni ọmọbinrin wọn a maa beere lọwọ oun pe nibo ni baba awọn wa ṣugbọn esi ti oun maa n fun un ni pe Baba rẹ ti ls darapọ ms awọn angẹli.
Gbajumọ oṣere naa ṣe apejuwe ọkọ rẹ Dudu Heritage gẹgẹ bi ọkunrin to ni itẹlọrun ati oruks rere nitori o gbagbọ pe orukọ rere san ju wura ati Fadaka. O ni Ọkọ to fun oun iyawo rẹ atawọn ọmọ ni ifọkanbalẹ ni. Ẹrin rẹ a si maa ran ka gbogbo ile.
Wọn sinku Dudu Heritage nilu Ibadan

Eto isinkun gbajugbaja oniṣowo, to tun jẹ ọkọ gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Bimbo Oshin, iyẹn Ola Ibiropnke ti ọpọ eeyan mọ si Dudu Heritage ti waye nilu Ibadan.
Ori papa ti wọn ti n gba ẹyin orilẹ ilẹ pẹlu igi sinu iho, Ibadan Golf Club ni eto naa ti kọkọ bẹrẹ.
Wọn bẹrẹ eto ọhun pẹlu gbingbin igi kan ni gbagede ti wọn ti n gba gọọfu naa lati ṣe iranti rẹ, ati lati ṣe apẹrẹ pe bo tilẹ jẹ pe o ti jade laye, yoo si wa laaye sibẹ.
- "A ti fòfin de ìdẹ́yẹsí nítorí ẹ̀yà ara ìbálòpọ̀ lójú òpó Facebook"
- Ẹ wo bí arákùnrin kan ṣe fi ọrún àti ọfà pa èèyàn márún ún
- "Akitiyan wa ti ń so èso rere, àdínkù ti ń bá bí àwọn agbésùmọ̀mí ṣe ń kọlu àwọn ọmọ Naijiria"
- "Á fimú Odunlade Adekola dánrin tó bá kọ̀ láti ṣe àtúnṣe lórí títàbùkù ẹ̀sìn Islam nínú fíìmù rẹ̀"
- Ọ̀lọ́pàá 34,587 níjọba àpapọ̀ ń rán lọ Anambra láti kojú agbébọn tó bá gbémú
- Wo aṣòfin àpapọ̀ tó fẹ́ káwọn káfíńtà àti dẹ́rẹ́ba ọlọ́kọ̀ èrò má san owó orí, Ó ní owó kékéré kó ni wọ́n rí
- Buhari, wá nǹkan ṣe sí àwọn agbésùmọ̀mí àti agbébọn tó ń pẹ̀ka bí ìrókò-Afenifere
- Iyorchia Ayu di alága tuntun fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
Ọpọ awọn oṣere tiata Yoruba lo peju sibi eto itiju naa.
Lara awọn agba oṣere to wa nibẹ ni, Adewale Adeoye, ti ọpọ eeyan mọ mọ si Adewale Elesho ẹnu n ja waya.

Elesho sọ fun BBC Yoruba pe Dudu Herigate jẹ ẹnikan to lawọ gidi to si maa n fẹ ki itẹsiwaju ba ẹlomiran.
Bakan naa lo ni Dudu Hertiage kii ṣe ẹni to ni ahun, o si maa lawọ lati ṣe ore fun ọpọ eeyan.

Ẹwẹ, ọrẹ timọ-timọ si oloogbe ọhun, to tun jẹ mbalogun ẹgbẹ awọn to n gab gọọfu, amofin Idowu Salami sọ fun BBC pe ẹgbẹ awọn to n gba gọọfu naa n ṣedaro oloogbe.
O fi kun pe inu ọgba Ibadan Golf Club naa gangan ni Dudu wa nigba ti ọlọjọ de.













