Odunlade THURIST: Ọmọ Mùsùlùmí ni mí, mí ò gbèrò láti fi sinimá 'Iku Ni' tàbùkù ẹ̀sìn mi- Olufunmi Baka

Oríṣun àwòrán, Instagram/Olufunmi Bakare
Oṣerebinrin to gbe sinima Ikú Ni jade, Olufunmi Bakare, ti tọrọ idariji lọwọ awọn ẹlẹsin Islam ti sinima naa bi ninu. Saaju ni ẹgbẹ́ ajafẹtọ ẹsin Musulumi kan, Ta'awunu Human Rights of Nigeria, THURIST ti fi ẹhonu han lori sinima naa ti wọn lo tabuku bá ẹsin awọn. Ninu sinima naa ni wọn ti safihan obìnrin ẹlẹha kan to ya were, to si n hu iwakiwa.
- Odunlade, a fún ọ lọ́jọ́ méje, yọ sinimá tó ń fi ẹlẹ́hàá ṣe yẹ̀yẹ́ kúró lórí ayélujára - Ẹgbẹ́ THURIST
- Tọ́mọ bá dára ó yẹ ká wí, ẹ wo Odunlade ọmọ Adekola
- Odunlade Adekola yarí lórí ìròyìn tó ní ó n bá àwọn obìnrin sùn kó tó fi wọ́n sínú fíímù rẹ̀
- 'Olóyè Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ kánmọ́ kánmọ́ ráńṣẹ́ láti Cotonou nípà owó ìtọ́jú ìlera rẹ̀'
- ₦500 tí màá fi ra 'Data' láti fí ṣé Yahoo-yahoo ló mú mí yín ọlọ́kadà lọrùn pa
Eyi si lo mu ki ẹgbẹ THURIST fi ikilọ ati idunkooko sita fun Odunlade Adekola, to jẹ ọkan lara awọn oṣere to kopa ninu sinima naa, ti wọn ro pe oun lo kọ ọ. Sugbọn oṣerebinrin Olufunmi ti ṣalaye pe oun ni oun kọ sinima naa. Ninu fidio to fi si ori ayelujara Instagram rẹ ni ọjọ Aiku ati ọjọ Aje, lo ti ṣalaye pe ọmọ idile musulumi ni oun, ti oun naa si n ṣe ẹsin naa. Arabinrin Olufunmi Bakare sọ pe oun ko gbe sinima naa jade lati tabuku ẹsin naa.

Oríṣun àwòrán, Odunlade Adekola
O ni iṣẹ owo ni Odunlade ṣe ninu sinima naa, kii ṣe oun ni oludari tabi ẹni to kọ sinima naa. O sọ pe idi ti oun fi ni ki obinrin were naa wọ aṣọ ẹlẹha ni pe ki awọn eero inu ọkọ to wọ̀ ma ba a dá mọ. Bakan naa lo sọ pe ki gbogbo awọn ẹgbẹ́ ẹsin Islam ti sinima naa ba binu darijin oun. O tun sọ pe oun ti yọ sinima naa kuro ni gbogbo ojú opo to n ṣe afihan rẹ, ki awọn le ṣe atunse to yẹ lori rẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
A fẹ ki wọn fi iya jẹ Oṣere Odunlade Adekola gẹgẹ bo ṣe wa ninu ilana ofin ẹgbẹ TAMPAN
Ẹgbẹ ajafẹtọ ẹsin Musulumi kan, Ta'awunu Human Rights of Nigeria ti tun wu ọrọ irunu mii sita lorii fiimu ti gbajugbaja oṣere, Odunlade Adekola gbe jade eyi ti wọn ni o tabuku awọn obinrin ẹlẹsin Islam.
Nibayii wọn tun ti lọ́ ẹsun ọhun mọ obinrin to ko ipa Ẹlẹhaa ninu fiimu naa, Arabinrin Olufunmi Bakare.
Wọn yari pe Odunlade mọọmọ ṣe fiimu naa jade lati tabuku awọn obinrin to n boju ninu ẹsin Islam ni to tun ni ibi ti Ẹlẹhaa ọhun n wọ motọ lọ ninu fiimu naa, Iyanna Ọrun, ko sibi to n jẹ bẹẹ nibikibi ni Naijiria.
Ẹgbẹ THURIST ni awọn ti gbọ oniruuru ọrọ ti awọn eeyan n sọ kiri nigba ti awọn fi aidunu han si nkan ti oṣere naa ṣe.
"A fẹ jẹ ki gbogbo eniyan mọ pe a ti gba ọpọlọpọ esi ati ipe ti awọn eeyan fẹ fi ṣi awọn araalu lọkan pe gbajumọ oṣere nni Odunlade Adekola ko ipa ribiribi ninu fiimu naa oun naa si ni o ni fiimu naa.
A fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe a ni ikọ ọtẹlẹmuyẹ tiwa to maa n fun wa ni iroyin kikakia to si ṣee gbagbọ torinaa a o le jẹ ki ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ ka lroi ayelujara to ṣẹ jade lẹyin taa fẹsun kan wa gbona ju ohun taa n sọ lọ. A ti fi ẹsun kan to si jẹ ootọ, a ṣi n duro lori ọrọ wa".
Wọn ni oṣere naa ba wa gbagbọ pe ẹsun odi lawọn fi kan an, ko jade wa lati sọrọ ni gbangba.
- Odunlade, a fún ọ lọ́jọ́ méje, yọ sinimá tó ń fi ẹlẹ́hàá ṣe yẹ̀yẹ́ kúró lórí ayélujára - Ẹgbẹ́ THURIST
- "Á fimú Odunlade Adekola dánrin tó bá kọ̀ láti ṣe àtúnṣe lórí títàbùkù ẹ̀sìn Islam nínú fíìmù rẹ̀"
- Odunlade Adekola yarí lórí ìròyìn tó ní ó n bá àwọn obìnrin sùn kó tó fi wọ́n sínú fíímù rẹ̀
- Wo bí Nkechi Blessing ṣe dákú rọngbọndan níbí ìsìnkú ìyá rẹ̀ l'Eko
"Bakan naa, a fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ni ibamu pẹlu jija fẹtọ ẹni ni ẹgbẹ yii fi tun fi ẹsun kan Arabinrin Olufunmi Bakare pẹlu Ọgbẹni Odunlade Adekola ati ẹgbẹ TAMPAN to n ṣakoso awọn oṣere fiimu Yoruba pe wọn kuna lati yẹ fiimu ọhun wo tabi fofin de iru rẹ".
Wọn ni awọn da obinrin naa ati Odunlade papọ ninu ẹsun yii tori pe o ṣeeṣe ki Odunlade ti beere lati lo obinrin naa Olufunmi ki ọwọ ofin ma baa muu.
"Amọ a fi n daa yin loju pe gbogbo ẹnikẹni to ba kopa ninu ere naa yala ipa kekere tabi nla, Musulumi ni tabi kii ṣe Musulumi lai fi ti ipo wọn ṣe la o ko pọ bi asiko ba to tori inu bi wa gidi fun ọna ti wọn gba ṣafihan Ẹlẹhaa naa.

Oríṣun àwòrán, Odunlade Adekola/Instagram
Fun idi eyi, awọn koko mẹrin ti a n beere fun laarin ẹgbẹ TAMPAN ati Ọgbẹni Odunlade Adekola niwọnyii:
1. Dida gbogbo ipele to ba ku ninu sinima "Iku Ni" duro ki wọn si ko o kuro lori gbogbo awọn oju opo ayelujara to ba wa to fi mọ Youtube laarin ọjọ meje.
2. fifi iya to tọ jẹ ẹni to gbe fiimu naa jade, odunlade Adekola ni ibamu pẹlu ohun ti ofin ati alakalẹ ẹgbẹ TAMPAN sọ.
3. Ṣiṣe ayẹwo fiimu gbogbo awọn oṣere to ba tun fẹ gbe iru nkan bayii jade.
4. Ki wọn pọn ọn ni dandan fun oṣere to ni fiimu naa lati tuba fun ẹgbẹ Musulumi ọhun fun iru fiimu to gbe jade yii nipasẹ ilana ti tile toko yoo rii.
"Inu wa dun pe BBC Yoruba jẹ ka mọ pe aarẹ ẹgbẹ TAMPAN Ọgbẹni Bolaji Amusan ti a mọ si Mr Latin ti ni oun yoo to sọrọ sita lori ipẹjọ wa yii".
Wọn ni awọn fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe ipẹjọ awn ko i ku lori ọrọ yii o pe o ṣi wa laaye am pabanbari ohun tawọn fẹ ni ki ati Ọgbẹni Odunlade ati TAMPAN tọrọ aforijin ni gbangba laarin ọjọ meje.
Eyi waye ninu atẹjade ti Agbẹjọro AbdulHakeem Abdul-Lateef ati Agbẹjọro Abdulsalama Abdul Fattah jọ fọwọ si ti wọn si ni bi Odunlade ati TAMPAN ko ba ṣe nkan tawọn n fẹ, awọn yoo gbe igbesẹ to lagbara ti awọn o si ni sọ bayii.

















