Kogi State Police Command: Àwọn ọlọ́pàá mẹ́ta tó gba N25000 ní ọwọ́ aráàlú ní ojú pópó tí wà ní páńpẹ́

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kogi ti ni ọwọ awọn ti tẹ ọlọpaa mẹta to ṣe aṣemaṣe pẹlu arinrinajọ ni ipinlẹ Kogi.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kogi, DSP William Ovye Aya ninu atẹjade ti wọn fi lede ni kete ti awọn ri fidio to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara naa ni awọn ti bẹrẹ si ni wa awọn ọlọpaa naa.
Fidio naa ṣafihan awọn araalu ti wọn wa loju kan naa ni oju popo ti ọlọpaa si n ba wọn ja pẹlu ibọn ni ọwọ rẹ.
- Ìdí rèé tí Oluwo ìlú Ìwo kò fi tíì gbé ìyàwó míìràn gẹ́gẹ́ bí Olórí láàfin
- Gómìnà Kwara ti pada sọ̀rọ̀ lóríi aáwọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Lai Mohammed, ǹkan ki síbẹ̀
- Wo bí Nkechi Blessing ṣe dákú rọngbọndan níbí ìsìnkú ìyá rẹ̀ l'Eko
- Báyìí ni mo ṣe san nínú oore Ọlọ́run tó fi Kábíyèsì Ooni ti Ile Ife ta èmi Silekunola lọ́rẹ - Olorì Wòlíì Naomi
- 'Èmi àti ìyá mi gbádùn láti máa bá ọkọ mi lájọṣepọ̀, ìdí tí mo fi gbà rèé'
- Òkóbó ni mí àmọ́ ìyàwó mi gbà láti fẹ́ mi lẹ́yìn tí mo sọ fun un - Pásítọ̀ Olumide Oni
Lẹyin to beere ẹgbẹrun marundinlọgbọn naira lọwọ ọkan lara awọn ero ọkọ to tun fọ ẹlomiran to sọ wi pe nkan ti wọn ṣe ko dara to ni eti.
Ninu atẹjade wọn, ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ọlọpaa lati Adogo Division ti wọn wa ni oju popo Adogo-Okene ni wọn hu iwa aitọ yii.
Orukọ awọn to ṣe aṣemaṣe naa ni ASP Isah Barnabas, Inspector Ifediegwu Godwin, Sgt Emmanuel Ochima ati CPL Umameh Mathias.
Wọn fikun un pe CPL Umameh Mathias lo gba awọn to wa ninu ọkọ leti lasiko ti wọn n ba awọn ọlọpaa naa sọrọ.
Bakan naa ni wọn fikun pe wọn ti n fi ọrọ wa awọn ọlọpaa naa lẹnu ni ọna ileeṣẹ ti awọn ọlọpaa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa kesi awọn araalu pe wọn ṣi n tiraka lati kan si awọn ti wọn fi iya jẹ ninu fidio naa, ki wọn kan si wọn ti wọn ba ti ri atẹjade naa.
Wọn fi da awọn araalu loju pe gbogbo ọlọpaa to lọwọ ninu ihuwasi yii ko ni lọ lai jẹ iya ẹṣẹ rẹ, ko le jẹ ẹkọ fun awọn iyoku.
Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí fídíò tó sàfihan ọlọ́pàá tó fí ìyà jẹ aráàlú kan tórí N25,000 - Iléeṣẹ́ Ọlọpàá
Ileese olopaa lorileede Naijiria ni iwadii ti bere lori fidio to safihan ọlọpaa to n fi iya jẹ ara ilu loju popo ni agbegbe Okene, nipinlẹ Kogi.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa fi lede, Ọga Agba ọlọpaa, Usman Alkali Baba ni oun ti paṣẹ fun Kọmiṣọnna ọlọpaa nipinlẹ Kogi lati se iwadii iṣẹlẹ naa to dabi ẹni pe o waye ni agbegbe Kogi.
Fidio naa safihan awọn araalu ti wọn wa loju kan naa ni oju popo ti ọlọpaa si n ba wọn ja pẹlu ibọn ni ọwọ rẹ.
- Wo bí Nkechi Blessing ṣe dákú rọngbọndan níbí ìsìnkú ìyá rẹ̀ l'Eko
- Àwọn obìnrin ń ṣe igbéyàwó pẹ̀lú igi láti ṣààmì ètò ìdàgbàsókè ìlú wọn
- Obesere sàlàyé ipa rere tí Dudu Heritage kó nínú ìgbé ayé rẹ̀ àti bó ṣe di èèyàn
- ''Ìrírí mí rèé lóri bí mo ṣe fún ìbejì mí lóyún tó sì tún bí ọmọ méjì fún mi''
- "Ìbejì ní wá ṣùgbọ́n àyẹwò DNA ní baba ọtọ́ọ̀tọ̀ ló bí wà"
- Mà á dupò Ààrẹ tí Ọlọ́run àti ọmọ Naijiria bá gbà fún mí - Tunde Bakare
Ẹni to n salaye nkan to ṣẹlẹ ninu fidio naa ni ọkan lara awọn ero inu ọkọ ni wọn fẹ gba 25,000 naira ni ọwọ rẹ, pẹlu ẹsun pe o ji laptop to wa ni ọwọ rẹ ni.
Amọ arakunrin ti wọn fi ẹsun kan naa ni ohun elo ti oun nlo ni ileekọ ni, nitori akẹkọọ ni oun.
''Nkan to ṣẹlẹ ni pe awọn ọlọpaa da wa duro ni agbegbe Ikene ni ipinlẹ Kogi, ti wọn si bẹrẹ si ni wo awọn to wa ninu ọkọ.''
''Akẹkọọ to wa ni iwaju ọkọ ni wọn wo foonu rẹ, ti wọn si ni ki o mu 25,000 naira wa nitori o ji awọn ohun elo naa.''

Oríṣun àwòrán, Others
''Akẹkọọ naa kọ jalẹ ti wọn si bẹrẹ si ni naa, titi ti wọn fi ni ko pe awọn mọlẹbi rẹ, ti wọn fi owo ranṣẹ si''
''Awọn ọlọpaa naa kọkọ ni ko ''Transfer'' owo naa si ''account wọn'' amọ wọn tun ero wọn pa pe awọn ko ni fun ni account wọn mọ, amọ ki wọn lọ si idi ATM lati lọ gba owo naa.''
''Ọkan lara awọn ọlọpaa ti orukọ rẹ wa lara aṣọ rẹ ni Ogu Godwin, ri wọn si wa lati ẹka ''refublish Police'' ni ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kogi.''
- Èrò tó bá jáde wo Buhari wá fi irú ìyà tó ń jẹ wọ́n hàn-án ni, kìí ṣe ti ìfẹ́ - Afenifere, Ohaneze
- "Mo ti pa ọmọdé mẹ́wàá, mo sì ń mu ẹ̀jẹ̀ wọn"
- Mompha pàdánù èròjà olówó ìyebíye mọ̀kànlá sọ́wọ́ EFCC
- Bimbo Oshin ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọkọ rẹ̀ sọ fun un kó tó kú
- Àlàyé rèé lórí ohun tí ojú mi rí ní àhámọ́ - Chiwetalu Agu
- Agbébọn jí ìbejì ọba gbé àti èèyàn mẹta míì ní Kwara
- Wo àwọn ohun mẹ́jọ́ tí àwọn olólùfẹ́ gbọ̀dọ̀ ṣe lẹ́yìn ìbálòpọ̀
''Eleyii to tele ọkọ ero lọ si ATM naa bọ aṣọ ọlọpaa silẹ lati tẹle lọ gba owo naa ni ọwọ rẹ.''
Amọ Ọga Ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti kesi awọn araalu lati fi ọkan balẹ nitori gbogbo ohun to ṣokunkun nipa iṣẹlẹ naa ni awọn yoo tupalẹ lẹyin iwadii naa.
Ati wi pe ọlọpaa to ba jẹbi ẹsun naa yoo fi oju wina ofin, ti ko si ni lọ lai jiya ẹṣẹ rẹ.












