Oluwo of Iwo: Mí ò kánjú láti fẹ́ ìyàwó míìràn ìgbà tó bá yá náà ló yá

Aworan Oluwo

Oríṣun àwòrán, emperortelu1

Yoruba bọ wọn ni apọnle ko si fun ọba ti ko l'olori laafin ṣugbọn ọrọ yi ko ṣebi ẹni de eti Oluwo ilu Iwo Ọba Abdulrasheed Akanbi Telu1.

Idi ni pe Oluwo ti sọ ninu ifọrọwero kan pe oun ko kanju lati fẹ iyawo miran tori naa ki awọn eeyan lọ ṣe mẹdọ.

Oriade yi ti ọpọ mọ fun imura ati ọrọ ṣisọ ni aawọ waye laarin oun ati olori rẹ Chanel Chin ti awọn mejeeji si ti pinya to ọjọ mẹta.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo yi, Oluwo sọ nipa aṣa fifẹ iyawo to ju ẹyọkan lọ ati idi ti oun ko fi fẹ ju iyawo kan lọ.

O ni bi eeyan ba wo inu bibeeli eeyan yoo ri pe Isaac ati Jacob, iyawo pupọ ni wọn fẹ, koda ninu aṣa Yoruba, iru nkan bayi ko jẹ tuntun.

''Awọn baba wa a maa niyawo pupọ amọ emi gẹgẹ bi iranṣẹ araalu, mo nifẹ si iyawo kan.''

O ni fifẹ iyawo kan ni yoo jẹ ki oun le ṣe iṣẹ ilu ti oun yan laayo amọ ti agbara ati aaye ba wa o ṣeeṣe ki oun fẹ ju ẹyọkan lọ.

''Bi eeyan ba ṣe iṣẹ pupọ ni ita yoo ni lati sinmi. Bẹẹ lo si tun ni iṣẹ to pọ lati ṣe ninu ile. O ni lati ṣojuṣe rẹ nile lọdọ awọn iyawo rẹ ti wọn ba pọ''.

''Ṣugbọn to ba jẹ ẹyọkan ni, a ṣi le maa faradaa fun ara wa nitori ifẹ. A o jọ ṣiṣẹ ilu papọ ni''.

Nigba ti wọn beere lọdọ Oluwo boya awọn araalu n damu rẹ pupọ lori fifẹ iyawo mi o ni wọn ko daamu oun.

Oluwo ati Olori tẹlẹ

Oríṣun àwòrán, emperortelu1

Oba Rasheed ni oun mọ pe awọn araalu ko ni fẹ ki oun fẹ iyawo mi ti yoo fẹ fun oun ni majele jẹ.

''Fifẹ iyawo, kii ṣe nkan taa ṣe fun eeyan. Lati ọkan lo ti maa n wa.''

''Mo mọ pe awọn eeyan mi ko ni fẹ ki n fẹ iyawo mii ti yoo tori pe ko ri owo gba ti yoo si f fun mi ni majele jẹ''

Lati ọjọ ti iyawo mi tẹlẹ ti de aafin lo ti n sọ mi lọwọ ati ẹsẹ

Nipa ibaṣepọ rẹ pẹlu olori Chanel to kuro laafin, Oluwo ni awọn kan lo ran wa si aafin lati wa tabuku oun.

Aworan Oluwo

Oríṣun àwòrán, emperortelu1

O ni oun ko mọ ni Canada tẹlẹ bi kii ṣe igba to de Naijiria ati pe bo ti ṣe de aafin lo ti bẹrẹ si ni ka gbogbo ọrọ ati iṣe oun sori foonu.

''Ki lo de ti obinrin yoo fi maa rikọọdi eeyan fun odidi ọdun mẹrin? Nigba ti mo ka a mọ, o ni afi ki n san owo bomilaṣiri fun oun''.

Oluwo tẹsiwaju pe Olori Chanel ni oun yoo tu aṣiri ohun tawọn se tile fi jona bi ko ba san owo fun oun.

''Mo sọ fun un pe ko tu aṣiri to ba fẹ tu. Ayafi ti kii ba ṣe pe Olorun lo fi mi sori aleefa yi, ko si ẹni to le yọ mi. Olodumare pada da mi lare lori ọrọ yi''.